Adájọ́ àgbà ní Kwara búra fún ìgbìmọ̀ Tribuna lórí ìdìbò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó n bọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 9, 2024

Adájọ́ àgbà ní Kwara búra fún ìgbìmọ̀ Tribuna lórí ìdìbò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó n bọ̀


Lọsẹ to kọja yii ni adajọ agba nipinlẹ Kwara, Onidajọ Abiọdun Adebara bura fun igbimọ ti yoo gbọ ẹjọ awọn olufẹhonuhan ninu eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna.

Onidajọ Abiọdun Adebara sọ pe awọn igbimọ meji ọtọọtọ naa ni yoo gbọ ẹjọ ti awọn ti eyo idibo ijọba ibilẹ to n bọ yii ko ba tẹ lọrun, lati le ṣe idajọ ododo.

Ọjọbọ tii ṣe Tọside ọsẹ to kọja ni adajọ agba ọhun bura fun igbimọ meji ọtọọtọ ni gbọngan ipade ti ile ẹjọ giga nipinlẹ ọhun.

Nibẹ ni adajọ agba ti sọ pe o ṣe pataki pupọ lati gbe igbimọ yii dide, lati ma ṣe jẹ ki wọn gba ẹtọ awọn kan lọwọ wọn lọna ti ko ba ofin mu.

O wa gba gbogbo awọn ọmọ igbimọ naa lamọran lati tẹle otitọ ninu gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe, bẹẹ lo ni ki wọn ma ṣe ojusaaju nigba ti wọn ba n ṣiṣe wọn.

Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni Onidajọ Majisirati Jibril Bio Salihu to jẹ alaga igbimọ akọkọ; Majisreeti Aluko ati Majisreeti Adeniyi Oluwaseyi Moses.

Majisreeti Abubakar Mohammed Ndakene ni alaga igbimọ keji nigba ti awọn bii Majisreeti Adebola Mercy Feyisayo ati Onidajọ AbdulHamid Yusuf Olatunji jẹ ọmọ ẹgbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI