AbdulRazaq búra fún adájọ́ tuntun mẹ́fà ní Kwara, ó tún gbé ọkọ̀ bọ̀gìnnì fún wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 15, 2024

AbdulRazaq búra fún adájọ́ tuntun mẹ́fà ní Kwara, ó tún gbé ọkọ̀ bọ̀gìnnì fún wọn


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe iṣakoso oun yoo tubọ maa ṣe iranwọ ati atilẹyin fun ẹka eto idajọ nipinlẹ maa.

AbdulRazaq lo sọ ọrọ yii lasiko to n bura fun awọn adajọ tuntun nipinlẹ naa laipẹ yii niluu Ilọrin.

Yatọ si ileri yii, gomina fi ọkọ bọginni SUV ta awọn adajọ mẹfa ọhun lọrẹ lati maa fi ṣẹsẹ rin fun agbelarugẹ iṣẹ wọn.

Awọn adajọ tuntun naa ni: Ibijoke Olabisi Olawoyin; Fatimah Funsho Abdulrasaq; Oluwatosin Adenike Adeniyi; Yusuf Diko Adebayo; Olalekan Osuolale Ajayi; ati Muritala Folohunsho.

"Ẹ ko gbọdọ ṣe ojusaaju tabi gbe lẹyin ẹnikẹni nigba ti ẹ ba n ṣiṣẹ yin fun aabo ilẹ yii."

Gomina AbdulRazaq gbe oriyin fun wọn lori ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gba, to si loun nigbagbọ pe wọn yoo ṣiṣẹ wọn bo ti tọ, ati bo ti yẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI