Ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ondo ti ju Baalẹ ilu Ebute Iparẹ to wa nijọba ibilẹ Ilajẹ, Oloye Francis Ogundeji sẹwọn ọdun mẹta gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ẹsun ti wọn fi kan Baale Ogundeji ni pe o kọ eti ikun si aṣẹ ile-ẹjọ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii, Onidajọ E. A Manuwa paṣẹ pe Ogundeji jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ogundeji ati ẹnikan to n jẹ Ikuejamoye Thomas ni wọn fi ẹsun kan ninu oṣu kọkanla, ọdun 2022 wi pe wọn ta ilẹ ni agbegbe wọn, eyi to tapa si aṣẹ ile-ẹjọ to wa nilẹ.
AWIKONKO gbọ pe ile-ẹjọ giga to wa niluu Okitipupa ati ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Igbọkọda ti gbe paṣẹ wi pe ẹnikẹni ko gbọdọ de ori ilẹ naa, ṣugbọn ti wọn sọ pe Ogundeji gbimọ papọ pẹlu Thomas lati ji ilẹ naa ta.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni awọn mejeeji tun yi iwe ti wọn fi ta ilẹ naa bi ẹni pe wọn ti ta ilẹ ọhun tipẹ, eyi to mu ki wọn fẹsun mẹrin ọtọọtọ kan wọn wi pe wọn tapa si aṣẹ ile-ẹjọ ati irọ pipa.
Ki adajọ too gbe idajọ naa kalẹ, la gbọ pe wọn ti kọkọ ka a si awọn olujẹjọ mejeeji naa leti lede Oyinbo, ṣugbọn ti wọn pada tunmọ rẹ fun wọn lede Yoruba.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn naa la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006 ni abala 517.
Ile-ẹjọ wa sọ pe ẹnikọọkan wọn ni anfaani lati san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọfa naira lori ẹsun kẹta.
Ṣugbọn sibẹ, ile-ẹjọ da Thomas lare lori ẹsun kinni, ekeji ati ẹsun kẹta.
Siwaju sii, ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki Ogundeji fi ẹwọn oṣu mẹta gbara lori ẹsun kinni, tabi ko lọ san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira sapo ijọba gẹgẹ bi owo itanran.
Ko tan sibẹ, ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki Ogundeji lọ sẹwọn oṣu mẹta lori ẹsun keji, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira sapo ijọba.
No comments:
Post a Comment