UBEC kò bu ẹnu àtẹ́ lu ilé-ẹ̀kọ́ kankan ní Kwara - Àwọn alákòso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 15, 2024

UBEC kò bu ẹnu àtẹ́ lu ilé-ẹ̀kọ́ kankan ní Kwara - Àwọn alákòso


Awọn alakoso ajọ to n ṣagbatẹru eto ẹkọ ni Naijiria, Universal Basic Education Commission (UBEC), ẹka tipinlẹ Kwara ti sọ pe kẹnikẹni ma ṣe gba ayederu iroyin to n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara nipa wi pe awọn ṣe ikọlu si ọkan lara awọn ile-ẹkọ nipinlẹ naa.

UBEC sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ti wọn kọ lati ba orukọ wọn jẹ, ati lati tako ijọba ipinlẹ naa ni, ti wọn si ni awọn ko le kawọ gbera lori rẹ.
 
Ninu atẹjade akọwe iroyin UBEC, Atẹrẹ Aminat Abiọla gbe jade lonii, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ni wọn ti ṣalaye pe awọn ko bu ẹnu atẹ lu ile-ẹkọ kankan ni Kwara.

Wọn ni ero ori akọroyin naa lo kọ jade lai ṣe iwadii kikun.

Atẹjade ọhun sọ pe amugbalẹgbẹ pataki fun UBEC ES, Unwaha Yahaya Ismaila fi lẹta kan ranṣẹ si alakoso agba UBEC ni Kwara, Ọjọgbọn Shehu Raheem Adaramaja lọjọ kẹsan, oṣu Kẹjọ, nibẹ lo si ti sọ pe “Wọn fun mi itọni lati sọ fun un yin pe lasiko ti akọwe UBEC ṣabẹwo si idanilẹkọọ kan to waye niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, oun ko figba kankan sọrọ nibẹ, paapaa wi pe boya oun bu ẹnu atẹ lu ipele ti eto ẹkọ ni Kogi, Kwara ati awọn ipinlẹ miran wa.

“Oun to jade nibẹ ni pe idanilẹkọọ ọhun to waye niluu Ibadan, awọn akopa lati ipinlẹ bii Kogi, Kwara ati awọn agbegbe miran lẹkun Guusu ilẹ Naijiria ni wọn ti wa, ati pe irufẹ idanilẹkọọ ọhun tun n lọ lọwọ ni Bauchi fun awọn akopa lati ẹkun Ariwa. Eyi ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ipo ti eto ẹkọ wa lawọn ipinlẹ naa.

“Ajọ UBEC yii ṣakiyesi irufẹ ipa ti iroyin ẹlẹjẹ naa yoo ko, ṣugbọn ti ẹ ni lati fọkan balẹ wi pe awọn alakoso ko nii gbe iru igbesẹ lati ba oju ijọba jẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI