Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan, Adekunle Adebanjọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kunle Polly lori iku awọn meje kan ti awọn naa tun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla fi sita lopin ọsẹ to kọja yii, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2024 fidi rẹ mulẹ.
Gẹgẹ bi Odutọla ṣe sọ, o ni ọkan lara awọn araalu lo pe awọn ọlọpaa ẹkun Igbeba nipe pajawiri lọjọ kejila, oṣu kẹjọ nipa ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Araalu naa fi to ọlọpaa leti wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ṣeku pa ọkan lara awọn alatako wọn ti orukọ rẹ n jẹ ‘Mosquito’.
Ẹni naa ti wọn fi orukọ bo laṣiri sọ pe ikun ni wọn ti yinbọn fun ‘Mosquito’, to si tun jẹ ko di mimọ pe wọn ge ọwọ ọtun ‘Mosquito’ naa lọ.
Odutọla sọ pe Adebajo ti wọn fura si wi pe o wa lara awọn to pa ‘Mosquito’ lọwọ tẹ ni nnkan bi agogo mejila kọja iṣẹju mẹta oru ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2024 nibi to sapamọ si lagbegbe Iṣiwọ.
O tẹsiwaju pe iwadii kikun ti ọlọpaa ṣe lo jẹ ki aṣiri ibi ti wọn fi ṣe ibugbe tu si wọn lọwọ, ti wọn si tọpinpin wọn debẹ.
Siwaju sii ni Odutọla sọ pe bọwọ ṣe tẹ Kunle Polly, lo ti bẹrẹ sii ka boroboro bi ẹyẹ orofo, to si jẹwọ pe lotitọ loun jẹ ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ‘Ẹiyẹ’.
“Ọrọ ti Kunle Polly sọ lo jẹ ka lọ yẹ ile rẹ wo, ti a si ba ibọn ilewọ Beretta pẹlu ọtan ibọn mẹta, aake UTC meji ati awọn oogun abẹnugọngọ loriṣiriṣi nibẹ.
“Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati gba ọwọ osi ‘Mosquito’ ti wọn ge lọ, ati lati rọwọ to awọn yooku nibi ti wọn salọ.”
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ọga awọn, Abiọdun Alamutu ti wa fọkan awọn araalu balẹ wi pe igba ati iṣakoso awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yoo dohun igbagbe lagbegbe Iṣiwọ Ijẹbu.
“Alamutu ti ṣeleri wi pe ọwọ yoo tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku, ti wọn yoo si foju wọn ba ile-ẹjọ.”
No comments:
Post a Comment