Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn pàdánù bàbá rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 6, 2024

Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn pàdánù bàbá rẹ̀


Ọgbẹni Kayọde Akinmade to jẹ oludamọran pataki lori eto iroyin fun gomina ipinlẹ Ogun lo ti padanu baba rẹ sọwọ iku.

Oloye agba, Moses Ade Akinmade la gbọ pe o jade laye lọjọ Aje to kọja yii lẹyin aisan ọjọ ogbo.

Baba naa to jẹ Ọbamọluwa tiluu Idanre ni iroyin iku rẹ jade sita nigba ti ọmọ oloogbe naa to jẹ Oludamọran pataki kede rẹ loni, ọjọ Iṣẹgun.

Atẹjade ti Ọgbẹni Kayọde Akinmade fi sita lorukọ mọlẹbi sọ pe baba naa ko ipa ribiribi to pọ nigba aye rẹ lẹka eto iṣẹ agbẹ ati aṣa.

Bakan naa lo sọ pe awọn yoo kede eto isinku laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI