Tilu-tijo l'awọn ọmọ ilu Ilawo nile loko, to fi mọ awọn afẹnifẹre fi n ki Olori Ọmọlara MacGregor, aya Ọba Alexander Olusegun MacGregor, Olu tilu Orile Ilawọ nipinlẹ Ogun fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2024 ti a wa yii.
Ayẹyẹ ọjọ ibi ọhun to waye ni aafin Orile Ilawọ to wa niluu Abẹokuta ni awọn oloye at'awọn eeyan jankan-jankan ti peju lati ba Olori Ọmọlara ṣajọyọ.
Eyi ni yoo jẹ ayẹyẹ ọjọ ibi akọkọ ti Olori Ọmọlara, ẹni to tun jẹ Yeye Olokun gbogbo agbaye yoo ṣe niluu Ilawọ.
Nibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni aya Ọba MacGregor ti fi ẹmi imoore han si Kabiyesi ati awọn ọmọ ilu Ilawọ, pẹlu bi wọn ṣe tẹwọ gba a latigba to ti de si aafin, to si loun ko figba kankan kabamọ.
O wa ṣeleri wi pe oun yoo tubọ maa gbe ilu Ilawọ larugẹ kaakiri gbogbo agbaye.
Ṣaaju asiko yii ni Olori Ọmọlara ti lọ ṣe iranwọ fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama ti Unity, iyẹn Unity Secondary School to wa niluu Ilawọ.
Nibẹ lo ti gba wọn lamọran pe ki wọn kọju mọ eto ẹkọ wọn, nitori pe ẹkọ nikan lo le gbe wọn de ibi giga laye.
Diẹ lara awọn aworan
No comments:
Post a Comment