Ọlọ́pàá mú Kúnlé Àjàyí, olùdíje sípò Gómìnà l'Ondo lásìkò ìwọ́de - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2024

Ọlọ́pàá mú Kúnlé Àjàyí, olùdíje sípò Gómìnà l'Ondo lásìkò ìwọ́de


Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti rowo to oludije sipo gomina ti ọdun 2024 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC) nipinlẹ Ondo, Kunle Wizeman Ajayi.

Ọwọ tẹ Ajayi pẹlu ọkunrin kan, Patrick Owolabi, ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Take It Back (TIB) Movement.

Asiko ti iwọde fifi opin si ijọba ti ko dara #EndBadGovernance, eyi to fẹẹ pari lonii n lọ lọwọ niluu Akurẹ ni ọlọpaa mu ọkunrin naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, yatọ si Ajayi ati Owolabi ti ọlọpaa mu, ọwọ tun tẹ awọn bii Oluwatobi Akinkuotu, Kọlawọle Kumuyi, Ọlalekan Ọladẹhinde ati awọn miran.

Nigba ti wọn n kede idagbasoke naa loju opo ayelujara 'X' wọn, ẹgbẹ TIB Movement ti wa bu ẹnu atẹ lu iwa awọn ọlọpaa naa.

Wọn si n beere pe ki ileeṣẹ ọlọpaa fi Ajayi, Owolabi ati awọn yooku tọwọ tẹ silẹ 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI