Ògbólògbó afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì há l’Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2024

Ògbólògbó afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì há l’Ógùn


Boroboro lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ laipẹ yii n ka bi ajẹ ti aṣiri rẹ tu sita.

Agbegbe Ijoko to wa ni Sango-Ọta, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta lọwọ ti tẹ awọn mejeeji, Abiọdun Salami ati Destiny Adeọla.

Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa nigba to n ṣalaye lọjọ Aje, oni, o sọ pe ọjọ kẹjọ, oṣu yii lọwọ tẹ wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, agbegbe Sango-Ọta, Ijoko, ati awọn agbegbe to sunmọ wọn ti jẹ agbegbe ibẹru fawọn araalu lori iwa ikọlu, ija ẹgbẹ okunkun ati ipaniyan.

Odutọla ni Adeọla ati Salami lọwọ tẹ lasiko ti wọn pe jọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ yooku fun ipade, ko to di pe awọn kan ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo.

Loju ẹsẹ lo sọ pe awọn ọlọpaa kogberegbe ti wọn n gbgogun ti iwa idigunjale ti dide lati koju wọn, ko to di pe ọwọ tẹ awọn meji, ti awọn yooku si na papa bora.

O ni ibọn ilewọ alawọ eeru, egboogi oloro ati awọn nnkan ija oloro miran ni wọn ri ko nibi tọwọ ti tẹ awọn mejeeji yii.

“Lasiko ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo, Adeọla jẹwọ pe lotitọ loun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, ati pe ọdun 2022 ni wọn fa oun wọle lagbegbe Atan-Ọta.

“Igbesẹ ti n lọ lọwọ lati rọwọ to awọn yooku ti wọn na pap bora,” Odutọla ṣalaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI