Ọbásanjọ́ tú àṣírí owó tí àwọn sẹ́nétọ̀ àti aṣojú-ṣòfin n gbà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 11, 2024

Ọbásanjọ́ tú àṣírí owó tí àwọn sẹ́nétọ̀ àti aṣojú-ṣòfin n gbà


Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ ti tu aṣiri nla nipa owo oṣu ti awọn aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin n gba, to si ni ko ba ofin ati iwa ọmọluabi mu.

Ọbasanjọ lo sọrọ ọhun lasiko to n gba ikọ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin lalejo nile rẹ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti, Furaide.

Nibẹ ni Ọbasanjọ ti jẹ ko di mimọ pe iwa ọdaju ni owo oṣu ti awọn aṣofin ati aṣoju-ṣofin Naijiria n gba jẹ.

Agba alẹnulọrọ Naijiria ọhun sọ pe miliọnu lọna igba naira ni owo ti ẹnikọọkan n gba loṣooṣu, ti wọn si n ko araalu sinu ebi, iṣẹ ati oṣi.

O lo ba oun lọkan jẹ pe ko si eyikeji ninu aṣofin ilẹ Naijiria ti wọn kabamọ tabi ti wọn kọ lati gba owo oṣu nla naa, to si ni iwa ibajẹ nla ni.

Bakan naa lo sọ pe ireufẹ iwa yii lo ṣokunfa awọn adojukọ ati ipenija to n ba Naijiria finra lasiko yii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ni ti ẹyin, lai nii pẹ ọrọ sọ, ko yẹ ko jẹ pe ẹyin lẹ ma maa sọ iye owo oṣu to yẹ ko tọ sii yin.

“Ṣugbọn niṣe le pinnu lati maa san owo oṣu funra yin, gbogbo ajẹmọnu ati owo iwe iroyin ti ẹ n gba. Niṣe lẹ n fun ara yin ni oriṣiriṣi nnkan, ti ẹyin naa si mọ pe ko ba ofin mu, o ku diẹ kaato.

“Ẹyin aṣoju-ṣofin n ṣe eyi, bẹẹ naa si lawọn n aṣofin agba n ṣe e, ti ẹ si n fọwọ sọya. Awọn alakoso lo ni ẹtọ lati sọ iye owo to tọ sii yin. Igba miliọnu naira lẹ n gba.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI