Nnkan dé! Ogójì èèyàn dèrò ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta ní Kwara nítoró agbègbè tó dọ̀tí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2024

Nnkan dé! Ogójì èèyàn dèrò ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta ní Kwara nítoró agbègbè tó dọ̀tí


Ko din ni ogoji eeyan ti ile-ẹjọ Majisireeti ju sẹwọn oṣu mẹta gbako lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii lori ẹsun titapa si ofin eto ayika nipinlẹ Kwara.

Ẹwọn oṣu mẹta gbako ni ile-ẹjọ naa to jokoo siluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ju gbogbo wọn si pẹlu iṣẹ aṣekara.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu atẹjade ti Yakub Kamaldeen Aliagan to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ayika ati igbo nipinlẹ Kwara fi sita, o sọ pe oniruuru ẹsun ni wọn fi kan wọn, eyi to nii ṣe pẹlu imọtoto.

Onidajọ Saidu Tunde Abdulkareem nigba to n gbe idajọ kalẹ, jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan naa jẹbi ẹsun dida ilẹ sibi ti ko tọ, ṣiṣa irin lọna aitọ, ati mimu ohun ti kii ṣe ti wọn.

Gbogbo wọn pata ni wọn sọ niwaju adajọ ọhun pe lotitọ ni awọn jẹbi, ti wọn si bẹbẹ fun idariji.

Ẹbẹ yii gan lo jẹ ki Onidajọ Abdulkareem foju aanu wo wọn, to si ni ki ẹnikọọkan lọ san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran, iyẹn bi wọn ko ba fẹẹ fi ẹwọn oṣu mẹta gbara.

Ilu Ilọrin la gbọ pe ọwọ ti tẹ gbogbo awọn ogoji naa lori ẹsun yii.

Mọkanlelọgbọn ninu wọn ni wọn fẹsun dida ilẹ sibi ti ko tọ kan, nigba ti wọn fi ẹsun ṣiṣa irin ati ilẹ (baba-n-bola tabi bola-bola) kan awọn mẹsan yooku.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ti Aliagan fi sita, Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati igbo, Ọnarebu Nafisat Buge sọ pe idagbasoke nla ni lati le jẹ ki imọtoto wa laarin ilu.

Ọnarebu Buge jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa yoo tubọ jẹ ki alaafia jọba lori ajakalẹ arun, omiyale ati oniruuru aisan to ṣee ṣe ko jẹyọ lati ara dida ilẹ sibi ti ko tọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI