Awọn agbesunmọmi ti ji iyawo Baalẹ ati awọn meji gbe wọnu igbo lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, abulẹ kan ti wọn pe ni Galadimawa nijọba ibilẹ Igabi, ipinlẹ Kaduna niṣẹlẹ ọhun ti waye.
Hussaini Umar, to jẹ Baalẹ ati Sarkin Fada Galadimawa abule kan lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin.
A gbọ pe niṣe ni wọn da ibọn bolẹ lasiko ti wọn wọ abule naa lati fi dẹru ba awọn araalu, ko to di pe wọn ja ilẹkun wọle.
Iyawo Baalẹ, Fatima; awọn ọmọ rẹ mejeeji, Abdullahi ati Kamal ni wọn fi ibọn jigbe salọ.
Umar sọ pe “Ẹmi wa ko de, ti a si wa ninu ewu nitori pe iyawo keji Baalẹ wa ati aw]on ọmọ rẹ mejeeji ni awọn agbesunmọmi naa jigbe lasiko ti wọn ko ogun wọlu.”
Umar lo darukọ Baalẹ naa gẹgẹ bii Alaaji Aliyu Haruna Galadimawa
O ṣalaye pe awọn agbesunmọmi naa gbọn gbogbo inu ile Baalẹ tuutu, to fi mọ ori orule ati ara ogiri, to si jẹ pe igba ti wọn ko ri Baalẹ ni wọn ko awọn mọlẹbi rẹ lọ.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni agbẹnusọ ọlọpa ipinlẹ Kaduna, ASP Mansir Hassan, ko tii fidi iroyin ọhun mulẹ.
No comments:
Post a Comment