Nkò yá owó ní bánkì, nkò sì tọrọ owó kí n tó ná bílíọ̀nù kan àtààbọ̀ náírà sí 'Film Village' mi - Ibrahim Chatta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 15, 2024

Nkò yá owó ní bánkì, nkò sì tọrọ owó kí n tó ná bílíọ̀nù kan àtààbọ̀ náírà sí 'Film Village' mi - Ibrahim Chatta


Gbajugbaja oṣerekunrin nni, Ibrahim Abiọdun Chatta lo ma ti sọ pe oun ko ya owo ni banki, bẹẹ si loun ko tọrọ owo lọwọ ẹnikẹni tabi fi kọ abule tiata, iyẹn Film Village oun.

Ibrahim Chatta sọ pe tọrọ-kọbọ toun n ri ni oun n lo lati fi kọ abule tiata naa, ati pe oun ko ṣe ojukokoro tabi sare ti ko yẹ lori rẹ.

Ogbontarigi oṣere tiata to mọ nipa aṣa, iṣe ati lilo ede Yoruba lọna to tọ sọ pe abule naa loun ti ya iṣẹ agbelewo toun pe ni Olokiki Oru.

O jẹ ko di mimọ pe asiko toun fee ya sinima oloyinbo kan to pe ni Voiceless ni ajakalẹ arun Korona wọle de, to si fa idaduro.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ọna toun fẹẹ gba ṣe ifẹyinti oun nidi iṣẹ tiata nigba naa yatọ si erongba ọpọ eeyan.

Ẹ gbọ ẹkunrẹrẹ ninu fọnran yii:



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI