‘Mo máa ju Mark Zuckerberg sẹ́wọn gbére’ – Trump - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 30, 2024

‘Mo máa ju Mark Zuckerberg sẹ́wọn gbére’ – Trump


Aarẹ ana nilẹ Amẹrika, Donald Trump lo ti ṣeleri lati ju alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Meta, iyẹn Mark Zukerberg sẹwọn gbere.

Donal Trump lo tu aṣiri yii ninu iwe kan to ṣẹṣẹ kọ, eyi ti yoo gbe jade sita lọsẹ to n bọ, nibi to fẹsun oriṣiriṣi kan Zuckerberg to ni Facebook, Instagram, WhatsApp ati awọn miran.

Gẹgẹ bi iroyin Politico ṣe gbe e jade, iwe ọhun ti Trump pe akọle rẹ ni ‘Saving America’, lo ti ni Zuckerberg wa lara awọn mu ijakulẹ ba oun ninu eto idibo ọdun 2020 to gbe Aarẹ Joe Biden wọle.

Trump sọ siwaju ninu iwe ọhun pe bi alaṣẹ Facebook ba tun gbiyanju lati ṣẹ si oun lẹẹkeji, niṣe ni “yoo lo eyi to ku nigbesi aye rẹ lẹwọn.”

Ninu iwe naa ni Trump ti ṣafihan aworan oun ati Zuckerberg ni White House.

Politico sọ pe ninu akọle ti Trump kọ sabẹ aworan ọhun lo ti ni ọdọkunrin naa “yoo wa ba oun ni ọfiisi Oval lati ri mi. O maa mu iyawo rẹ to dara wa jẹ ounjẹ alẹ, yoo si ṣebi ẹni to ni iwa ọmọluabi, nigba to si jẹ pe niṣe lo n gbimọ lodi si mi, ninu igbimọ “PLOT AGAINST THE PRESIDENT.”

“A n wo iṣe rẹ finnifinni, to ba si ṣe ohun to lodi si ofin lasiko yii, o maa lo eyi to ku nigbesi aye rẹ lọgba ẹwọn – ati paapaa awọn to ba gba ọna alumọkọrọyi ninu eto idibo aarẹ ọdun 2024.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI