Lookman lọ́pọlọ bọ́ọ̀lù ju Osimhen lọ - Peseiro sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 24, 2024

Lookman lọ́pọlọ bọ́ọ̀lù ju Osimhen lọ - Peseiro sọrọ


Akọnimọ-ọn-gba tẹlẹ fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orileede Naijiria, Jose Peseiro ti sọ pe agbabọọlu ọwọ iwaju fun ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta nni, Ademọla Lookman ni ọpọlọ bọọlu ju akẹgbẹ rẹ toun wa ninu ẹgbẹ agbabọọlu Napoli, iyẹn Victor Osimhen lọ.

Peseiro sọ pe awọn agbọọlu mejeeji loun ti ba ṣiṣẹ pọ lasiko toun fi jẹ akọnimọ-ọn-gba Super Eagles, toun si mọ iwọn ti onikaluku wọn gbe.

Peseiro lo ko ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lọ fun idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika ti ọdun 2023 to waye lorileede Ivory Coast ni ibẹrẹ ọdun yii, nibi ti wọn ti ṣe ipo keji.

O sọrọ ọhun lori awuyewuye to n lọ nipa iṣipopada sinu ẹgbẹ agbabọọlu miran to nii ṣe pẹlu awọn agbabọọlu mejeeji.

Lookman ati Osimhen lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni wọn ti n lewaju ninu awọn ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal n woye lati ra, eyi to mu ki Peseiro sọ erongba rẹ nipa awọn mejeeji.

“Ademọla ni ọpọlọ imọ-ẹrọ bọọlu ju Osimhen lọ, to si tun mọ bo ṣe li yi ifẹsẹwọnsẹ pada, ẹni to tun ti wa n gba bọọsinu awọn. O n ṣe daadaa lọdun yii,” ohun ti Peseiro sọ fun SportItalia lati ọdọ Football London ree.

“O dagba sọwọ (akọnimọn-ọn-gba Atalanta) Gian Piero Gasperini; ni bayii, o ṣi tun n gba bọọlu, inu wa si dun sii. Ni ọna to ga, oun naa le ṣiṣẹ iwuri lati ṣe ohun to jọju.

“Kii ṣe sababi wi pe awọn mejeeji ti dagba ninu ere bọọlu lọdun yii. Eyi ni nitori pe wọn jọ wa ninu ilana to dara lati gba bọọlu ni. Atalanta ati Napoli nilo bọọlu: wọn fẹẹ gba bọọ idojukọ. Ninu igbesẹ yii, awọn agbabọọlu maa n ni itara bi eyi. Ere bọọlu ilẹ Italy ti mu ayipada ba ọpọ nnkan.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI