Lílo ọdún mẹ́fà lórí ipò ìṣàkóso kì í ṣe ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàíjíríà - Ọbásanjọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2024

Lílo ọdún mẹ́fà lórí ipò ìṣàkóso kì í ṣe ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàíjíríà - Ọbásanjọ́


Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to ti figba kan ri jẹ aarẹ lorileede Naijiria ti sọ pe fun awọn adari lati maa lo ọdun mẹfa gẹgẹ bii saa iṣakoso kan ṣoṣo kii ṣe ọna abayọ si iṣoro to n dojukọ orileede ọhun.

Ọbasanjọ sọ pe ọna abayọ kan ṣoṣo lo le mu ki idagbasoke ati ilọsiwaju wa nilẹ Naijiria ni ki irori ati ironu awọn alakoso yatọ, ko si jẹ eyi ti yoo jẹ nipa ifẹ ilu ati orileede.

Ẹbọra Owu lo sọrọ naa lasiko to n gba awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja lalejo nile rẹ to wa nile ikawẹ aarẹ, iyẹn OOPL niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti, ana.

Alẹnulọrọ ilẹ Naijiria naa sọ pe ohun ti ko dara ni ki awọn to wa ni ijọba maa gbadun ara wọn, ki wọn si maa sọ fun awọn araalu to n jiṣẹ-jiya pe ki wọn ṣe suuru.

Ọbasanjọ kọminu gidi lori bi awọn aarẹ to gba ipo lẹyin rẹ ko gunle ilana ati eto to fi silẹ ko tii gbe ipo aarẹ silẹ lọdun 2007.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ju ohunkohun lọ, bii yiyi ilana iṣejọba wa pada, tabi lilo agbekalẹ ọdun mẹfa tabi ọdun mẹrin lori ipo, a ni lati yi ọna ti a n gba ṣe n nnkan pada lorileede yii, a ni lati tun ọpọlọ wa ṣe si daadaa, ka si yi irori ati iwa wa pada.

“Yoo wu mi ki awọn ijọba to n gba ipo gunlẹ ipilẹ ti a fi lelẹ nigba ti wa, koda bi ko ba tiẹ yara kankan to eyi ti a n foju sọna fun. O ba ni lọkan jẹ pe gbogbo ohun ti a fi lelẹ ni wọn ti yọ kuro.

“Ohun ti mo mọ nipa Naijiria ni pe, bẹẹni, bi a ba ṣe ohun to tọ, adari, awọn ikọ, nitori pe igi kan ṣoṣo ko le da igbo ṣe - ẹ nilo adari gidi, ṣugbọn sibẹ, ẹ tun nilo awọn ikọ to dara lati le ṣiṣẹ iwuri.

Koko ibẹ ni pe bi a ba rii ṣe daadaa, laarin ọdun meji aabọ, a maa bori ọpọ ninu awọn adojukọ wa, ati pe laarin ọdun mẹwaa si asiko yii, a maa ni ipilẹ rere, ati paapaa laarin ọdun mẹẹdọgbọn, a maa de ibi ti a lero lati de.

“Ṣugbọn ti a maa n ṣe ni gbogbo igba ni pe ka gbe ẹsẹ kan siwaju, ka gbe ẹsẹ meji sẹgbẹ, ka si wa a gbe ẹsẹ mẹrin pada sẹyin, to si jẹ pe ohun lo fa ibi ti a ṣi wa lorileede yii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI