Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta: Kwara bẹ̀rẹ àtúnkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àtijọ́ sí tìgbàlódé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 29, 2024

Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta: Kwara bẹ̀rẹ àtúnkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àtijọ́ sí tìgbàlódé


Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ atunkọ ile atunkọ ọkan lara awọn ile-ẹkọ atijọ si ti igbalode, lojuna lati ba ẹgbẹ pe.
 
Eyii ni igbesẹ lara agbekalẹ eto ẹkọ igbalode tijọba Kwara dawọle
 
Ile alaja rẹpẹtẹ ni ijọba Kwara fẹẹ kọ ile ẹkọ yii, ko le ba awọn ile-ẹkọ igbalode kaakiri dọgba.

Latigba ti AbdulRahman AbdulRazaq ti di gomina, lo ti ṣeleri pe eto ẹkọ jẹ oun logun pupọ, toun yoo si sa gbogbo ipa oun lati rii pe awọn ọmọ ati olugbe jẹ anfaani eto ẹkọ igbalode.
 
Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Adeta to wa nijọba ibilẹ Ilorin West ni iṣẹ atunkọ ọhun ti bẹrẹ.
 
Ọdun 1960 ni wọn da ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Adeta silẹ niluu Ilọrin, to si wa lara awọn ile-ẹkọ atijọ ti Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri wi pe oun yoo ṣe atunkọ rẹ fun irọrun akẹkọọ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI