Lẹ́yin ọdún mẹ́rin látìmọ́lé, ọlapàá tú àwọn olùwọ́de #ENDSARS ọdún 2020 sílẹ̀ l’Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 24, 2024

Lẹ́yin ọdún mẹ́rin látìmọ́lé, ọlapàá tú àwọn olùwọ́de #ENDSARS ọdún 2020 sílẹ̀ l’Ékòó


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹti ṣalaye lori ti wọn ṣe tu awọn gendekunrin mẹrin ti wọn kopa ninu iwọde ifopin si ọlọpaa kogberegbe ti a mọ si SARS, iyẹn #ENDSARS ti ọdun 2020 silẹ.

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko lo paṣẹ lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 wi pe ki awọn mẹrin naa maa lọ sile layọ ati alaafia.

Lati ọdun 2020 ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn oluwọde ọhun, eyi ti awọn mẹrin yii wa lara wọn, to si jẹ pe latigba naa ni wọn ti wa lahamọ.

Itusilẹ wọn yii lo fa oriṣiriṣi awuyewuye lori ayelujara, nibi ti wọn ti n beere idi ti wọn fi pẹ to bẹẹ latimọle.

Nigba to n fesi si awọn ẹsun ti awọn ọmọ Naijiria fi kan wọn, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe kii ṣe nitori iwọde ni wọn ṣe ko wọn.

“A ko fọwọ ofin gbe wọn tabi foju wọn ba ile-ẹjọ fun kikopa ninu ifẹhonuhan. A foju wọn ba ile-ẹjọ lori ẹsun jija ile ati ole jija, eyi ti wọn ṣe pẹlu ọgbọn kikopa ninu iwọde #ENDSARS.

“Bo tilẹ jẹ pe wọn dajọ fun wọn, ṣugbọn ile ẹjọ ninu ọgbọn rẹ dariji wọn.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI