lẹ́yìn ikú Onweka, Sunny Ade tú àṣírí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárin wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2024

lẹ́yìn ikú Onweka, Sunny Ade tú àṣírí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárin wọn


Gbajugbaja onkọrin nni Juju nni, Oloye Sunday Adegẹye ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Sunny Ade kaakiri agbaye ti tu aṣiri nla to wa laaarin oun ati agba onkọrin-binrin to doloogbe laipẹ yii, Onweka Onwenu.

Sunday Ade lo tu aṣiri nla naa nibi abẹwo ibanikẹdun to ṣe lọ sile oloogbe naa, nibi to ti sọ pe ajọṣepọ awọn dan mọnran daadaa ko too jade laye.

Lati bi ọpọlọpọ ọdun ṣeyin ni oriṣiriṣi awuyewuye ati iroyin ti jade nipa Sunny Ade ati Onyeka Onwu, to fi jẹ ki ọpọ ro pe awọn mejeeji ni ifẹ ikọkọ.

Awọn mejeeji yii ni ko sọrọ lori awuyewuye naa fun ọjọ pipẹ, ko to di pe Onyeka ku, ti Sunny Ade si ti wa sọrọ sita.

Sunny Ade sọ pe lotitọ lawọn mejeeji jẹ ọrẹ timọtimọ, ṣugbọn nnkan to pa wọn pọ ko kọja iṣẹ orin kikọ ti wọn jọ yan laayo.

Ọkunrin naa sọ pe ohun to fa awuyewuye to lọ kaakiri igboro nipa awọn mejeeji ko kọja ti orin ti awọn jọ kọ papọ, eyi ti wọn pe ni ‘duro de mi’ (Wait for Me).

Aladegẹye gẹgẹ bi awọn kan tun ṣe maa n pe Sunday Ade sọ pe ohun to ṣẹlẹ naa ni lati ṣagbelarugẹ orin ti wọn jọ kọ papọ yii, ko le ta bi awọn ti lero, iyẹn lati le fi pawo gidi sapo.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “A fẹẹ fi orin ‘Wait for Me’ naa lelẹ. Tẹlẹ, awọn eeyan maa n ro pe ọrẹbinrin mi ni. Emi pẹlu ẹ ko tii figba kan sọ bẹẹni tabi bẹẹkọ.”

Nibẹ lo ti ṣapejuwe oloogbe Onwenu gẹgẹ bi alakikanju obinrin to da yatọ, to lo ṣe ọpọlọpọ iranwọ bii amọran ati ọrọ iṣiti foun nigba to wa laye.

“O jẹ ẹnikan to maa jokoo pẹlu rẹ. O maa n sabaa sọ pe ‘ṣe mo le wọle pẹlu awọn amọran kọọkan?’ Awọn amọran wọnyi si maa n ṣe daadaa lara ọtọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI