Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣeleri wi oun ko nii laju silẹ lati jẹ ki awọn oṣiṣẹ ijọba, paapaa oṣiṣẹ-fẹyinti jakejado ipinlẹ naa maa gbe ninu iṣẹ ati oṣi.
AbdulRazaq sọ pe iṣẹ ati oṣi laarin awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa ti di ohun igbagbe pẹlu oriṣiriṣi eto ironilagbara ti iṣakoso oun ṣagbekalẹ rẹ.
O ni lara awọn nnkan to jẹ oun logun, toun si gbọdọ gbajumọ ni ilọsiwaju, igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ nipa pipese agbegbe ti yoo mu igbe aye irọrun ba wọn lẹyin ti wọn ba fẹyinti
Gomina AbdulRazaq sọ eyi di mimọ l'Ọjọbọ, tii ṣe Tọside, ọsẹ yii nibi akanṣe eto ti wọn gbe kalẹ lati ro awọn oṣiṣẹ lagbara.
Nigba to n fi atilẹyin rẹ han si afojusun eto ti wọn pe ni Seventeen World Sustainable Development Goals, ijọba sọ pe lara eto ọhun ni lati rii daju pe agbegbe iṣẹ to rọrun lati ṣe wa fun awọn eeyan ati idagbasoke eto ọrọ aje.
"Awọn igba ati asiko ki oṣiṣẹ ijọba ni Kwara fẹyinti lẹnu iṣẹ, ki wọn si ma ṣe ri ohun ti wọn ma maa ṣe lati ri owo ti kọja. Ohun ti iṣakoso yii n ṣiṣẹ le lori ni lati gbajumọ ohun ti ẹ ma maa ṣe lẹyin ifẹyinti," igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi lo sọrọ naa nibi akanṣe eto Kwara SDGSs, akọkọ iru rẹ.
Alabi wa rọ awọn akopa lati lo eto naa gẹgẹ bi anfaani naa lati ṣiṣẹ takuntakun fun agbelarugẹ ipilẹ to jinlẹ fun ọjọ iwaju rere.
No comments:
Post a Comment