Iṣẹ́ abẹ ìdí ni Abíọ́lá lọ ṣe l’Ékòó, ló bá gbabẹ́ dèrò ọ̀run - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 30, 2024

Iṣẹ́ abẹ ìdí ni Abíọ́lá lọ ṣe l’Ékòó, ló bá gbabẹ́ dèrò ọ̀run


Ọdọmọbinrin kan ni iroyin ti fi to wa leti pe o ti dero ọrun alakeji, lẹyin ti idi to lọ ṣe lọsibitu kan niluu Ekoo yiwọ mọ-ọn lọwọ.

Abiọla ni wọn pe orukọ ọdọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji ọhun.

Ile iwosan kan to wa lagbegbe Lekki-Phase 1, ipinlẹ Eko ni wọn sọ pe Abiọla lọ lati ṣiṣẹ abẹ ti yoo jẹ ki ibadi rẹ tobi ju tẹlẹ lọ.

Nnkan bi agogo mẹta ọsan ọjọ Aje tii ṣe Mọnde ni a gbọ pe ọrọ yiwọ, ti Abiọla si gbabẹ dero ọrun alakeji.

Ṣiṣe iṣẹ abẹ lati le jẹ ki idi tobi wọpọ laarin awọn obinrin asiko yii, eyi ti wọn kakun rirẹwa gẹgẹ bi ọlọmọge, ati lati jẹ ki awọn ọkunrin maa sare tẹle wọn lẹyin.

Ọkan lara awọn to gbe iṣẹlẹ naa si awọn akọroyin leti jẹ ko di mimọ pe agbegbe Diamond Estate, to wa ni Ṣangotẹdo, Ibẹju Lekki ni Abiọla n gbe, nibẹ lo si ti kuro lọjọ naa lọ si ọsibitu.

Funra rẹ lo pe awakọ lati gbe oun lọ si ile iwosan fun iṣẹ abẹ.

Gbara to debẹ, ni wọn sọ pe dokita to n da a lohun paṣẹ fun nọọssi kan lati gun Abiọla ni abẹrẹ.

Ko pẹ ti Abiọla gba abẹrẹ ọhun lo di pe ọrọ yiwọ, to si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, ko to tun di pe o bẹrẹ sii pokaka iku.

Lati le doola ẹmi rẹ lo jẹ ki wọn sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu kan ni Lekki Phase 1, nibi to pada dakẹ si.

Benjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo sọ pe otitọ ni iṣẹlẹ ọhun, ati pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi to ṣokunfa iku Abiọla lọjọ Iṣẹgun to tẹle.

Hundeyin ni awakọ oloogbe naa lo wa ṣalaye iṣẹlẹ naa fun ọlọpaa ti ẹkun Marọkọ.

“Awakọ aladani ti oloogbe naa n lo, lo lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun Marọkọ lati fi ẹjọ sun. Awọn oṣiṣẹ wa lọ sibẹ lati ṣewadii, ti wọn si gbe oku naa lọ mọṣuari fun iwadii lara oku.

“Ọwọ ti tẹ nọọsi to gun Abiọla labẹrẹ, ti a si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI