Ìpínlẹ̀ Ògùn kò jẹ owó WAEC - Àwọn alákòóso WAEC sàlàyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 13, 2024

Ìpínlẹ̀ Ògùn kò jẹ owó WAEC - Àwọn alákòóso WAEC sàlàyé


Ajọ to n ṣakoso eto idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama ti a mọ si West Africa Examination Council (WAEC), ẹka tipinlẹ Ogun ti sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko jẹ awọn lowo.

Alakoso ajọ WAEC nipinlẹ Ogun, Ayọbami Suberu lo fi iroyin naa lede, to si ni ohun to ṣẹlẹ ti idanwo awọn akẹkọọ ko ṣe tii jade ni ti iṣoro ayelujara wọn.

Suberu sọ pe iroyin to n kaakiri wi pe ipinlẹ Ogun jẹ awọn lowo, leyi to fa ki wọn mai tii gbe esi idanwo awọn akẹkọọ ile ẹkọ ijọba sita kii ṣe otitọ.

Suberu sọ pe awọn to gbe iroyin naa jade ko ṣe iwadii kikun, ati pe wọn ko gbọ ọrọ lẹnu wọn lati mọ aridaju.

O ni ijọba ipinlẹ Ogun ko jẹ awọn lowo kankan, ati pe awọn ti wọn ko tii ri esi idanwo wọn wo, jẹ iṣoro ti awọn n koju, to si ni awọn ti n gbe igbesẹ lee lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI