Ileeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ní Nàíjíríà fa Onídàájọ́ Kékeré-Ẹkùn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ àgbà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 15, 2024

Ileeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ní Nàíjíríà fa Onídàájọ́ Kékeré-Ẹkùn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ àgbà


Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto idajọ lorileede Naijiria, eyi tii ṣe  National Judicial Council ti fa Onidajọ Kudirat Kekere-Ekun kalẹ gẹgẹ bi adajọ agba ilẹ naa.
 
Fifa ti wọn fa Kekere-Ẹkun kalẹ jẹ eyi ti wọn ṣe ni kanju-kanju nibi ipade pajawiri to waye laipẹ yii.
 
Ọjọ Ẹti, ọsẹ yii lo yẹ ki wọn fi orukọ ẹni yoo gba ipo adajọ agba lọwọ Onidajọ Olukayọde Ariwoọla to fẹẹ fẹyinti lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ṣugbọn ti wọn sare ṣepade pajawiri lori rẹ lonii, Ọjọbọ.
 
Bakan naa ni wọn tun fi orukọ awọn mẹtadinlọgbọn miran ranṣẹ gẹgẹ bi adajọ agba lawọn ipinlẹ kọọkan.
 

Ipade naa la gbọ pe o ṣi n lọ lọwọ lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Ẹkunrẹrẹ n bọ laipẹ...

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI