Ilé-iṣẹ́ Adron Homes ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 18, 2024

Ilé-iṣẹ́ Adron Homes ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dọ́


Gbajugbaja ileeṣẹ alaragbayida nni, Adron Homes ti gbe eto idanilẹkọọ nla kalẹ fun awọn ọdọ ti ko din ni ẹgbẹrun mẹta.

Idanilẹkọọ ọhun ti wọn pe ni 'Capacity Building', iyẹn ironilagbara nipa agbekalẹ okoowo lo waye nibi eto ipagọ idaji ọdun ti wọn pe ni 'Recharged National Convention'.

Nibi idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta gbako ọhun to waye ni ileeṣẹ Adron Homes to wa ni Shimawa, ipinlẹ Ogun, eyi to pari lọjọ Abamẹta to kọja yii ni awọn akopa ti sọ pe eto ọhun laami-laaka.

Oriṣiriṣi ẹka ti awọn ọdọ naa yan laayo la gbọ pe wọn ti gba idanilẹkọọ wọn.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI