Ile awoṣifila alaja mọkanla ti Gomina AbdulRazaq dawọle ti n pari lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 22, 2024

Ile awoṣifila alaja mọkanla ti Gomina AbdulRazaq dawọle ti n pari lọ


Pupọ awọn to gbọ nipa ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq kede wi pe ijọba oun yoo bẹrẹ kikọ ile alaja mọkanla, eyi ti yoo jẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ipawo-wọle ni wọn ko lero wi pe ohun to le ṣee ṣe ni.
 
Ile alaja mọkanla naa ni gomina pe ni Kwara Revenue House, nibi ti gbogbo awọn oṣiṣẹ to n ri sọrọ eto ipawo-wọle yoo maa lo nigba ti iṣẹ ba pari.
 
Awọran ipele ti iṣẹ de ninu ile alaja naa, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣafihan pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari.
 
Lara awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti ko wọpọ, eyi ti Gomina AbdulRazaq dawọ le ni ile alaja mọkanla yii ti wọn pe ni Kwara Revenue House.
 
Eyi yii si jẹ ohun aritọkasi ninu itan, bi wọn ba n sọ nipa gomina ọhun lọjọ iwaju.

Diẹ lara awọn aworan ibi ti iṣẹ de duro ree...





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI