Lojuna lati fopin si iṣẹ, oṣi ati aisi ounjẹ laarin ilu, ijọba ipinlẹ Kwara ti ko awọn ohun ọgbin fawọn agbẹ to wa kaakiri ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.
Awọn agbẹ ti wọn jẹ ojulowo, ti wọn si kaju oṣuwọn ni ijọba Kwara ko awọn ohun ọgbin naa fun lati gbin in.
AWIKONKO gbọ pe lẹyin iforukọsilẹ awọn agbẹ naa, ti ijọba si ṣe ayẹwo wọn finnifinni, ni wọn too ko awọn ohun ọgbin naa fun wọn.
Ni nnkan bi oṣu mẹta sẹyin ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq bẹrẹ ipele kẹta pinpin awọn ohun ọgbin naa, to fi mọ ajilẹ ati kẹmika fun ẹgbẹrun mẹwaa agbẹ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara.
Awọn agbẹ ọhun fi idunnu han si Gomina AbdulRazaq pẹlu ọrọ idupẹ.
No comments:
Post a Comment