Ìjọba Kwara fi àwọn ohun ọ̀gbìn ta àwọn àgbẹ̀ lọ̀rè - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 12, 2024

Ìjọba Kwara fi àwọn ohun ọ̀gbìn ta àwọn àgbẹ̀ lọ̀rè


Lojuna lati fopin si iṣẹ, oṣi ati aisi ounjẹ laarin ilu, ijọba ipinlẹ Kwara ti ko awọn ohun ọgbin fawọn agbẹ to wa kaakiri ijọba ibilẹ  nipinlẹ naa.

Awọn agbẹ ti wọn jẹ ojulowo, ti wọn si kaju oṣuwọn ni ijọba Kwara ko awọn ohun ọgbin naa fun lati gbin in.

AWIKONKO gbọ pe lẹyin iforukọsilẹ awọn agbẹ naa, ti ijọba si ṣe ayẹwo wọn finnifinni, ni wọn too ko awọn ohun ọgbin naa fun wọn.

Ni nnkan bi oṣu mẹta sẹyin ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq bẹrẹ ipele kẹta pinpin awọn ohun ọgbin naa, to fi mọ ajilẹ ati kẹmika fun ẹgbẹrun mẹwaa agbẹ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara.

Awọn agbẹ ọhun fi idunnu han si Gomina AbdulRazaq pẹlu ọrọ idupẹ.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI