Ìjà dópin: Mákindé ṣàbẹ̀wò sí Ládọjà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 9, 2024

Ìjà dópin: Mákindé ṣàbẹ̀wò sí Ládọjà


Ọpọ awọn to ri aworan ipade ti Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ ṣe lọ sile Sẹnetọ Raṣidi Adewọlu Ladọja ni wọn n kọrin ‘ija d’opin, ogun si tan...’, pẹlu igbagbọ wi pe aawọ to wa laarin wọn ti dohun igbagbe.

Kii ṣe iroyin tuntun pe aarin Gomina Makinde ati Sẹnetọ Ladọja toun naa ti ṣe gomina ipinlẹ naa ri ko gun rege, paapaa lori ipo Olubadan tilẹ Ibadan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ ti Olubadan tuntun, Ọba Ọlaotan Ọlakunlẹhin gba ade ni Gomina Makinde gbe ilana tuntun nipa jijẹ oye Olubadan jade sinu iwe eto ọjọ naa.

Nibẹ ni wọn ti sọ pe Oloye to ga julọ ti ko ba ti gba ade idẹ ko ni lanfaani lati jẹ oye Olubadan, leyi ti ko ṣenu rere fun Ladọja, to si bi awọn ọmọlẹyin baba naa ninu.

Ṣugbọn ninu ifọrọwerọ ti agba oṣelu naa sọ lori redio Fresh to wa niluu Ibadan lọjọ diẹ sẹyin lo ti sọ pe gbogbo oun ti yoo ba gba lati di Olubadan loun yoo fun un.

Ladọja sọ pe ko si ohun to le di oun lọna lati jẹ oye Olubadan bi Ọlọrun ba fẹ, ati pe riro t’ẹniyan, ṣiṣe ni ti Ọlọrun.

Ṣugbọn ninu aworan ti ọkan lara awọn alabaṣiṣẹpọ gomina, Akeem Azeez gbe soju opo fasibuuku rẹ laipẹ yii, o jẹ ko di mimọ pe Gomina Makinde ti lọ ṣe abẹwo alaafia ati iṣọkan si Oloye Ladọja to jẹ Ọtun Olubadan, ti wọn si jọ sọrọ.

Azeez sọ pe lara eto alakalẹ isinmi lẹnu iṣẹ fun Gomina Makinde, ati lati gba alaafia ati iṣọkan laate nipinlẹ naa ni abẹwo ọhun wa fun.


Ninu ọrọ to kọ, o ṣalaye pe “Ni ana, bi Gomina Ṣeyi Makinde ṣe bẹrẹ isinmi rẹ lẹnu iṣẹ, o ṣabẹwo fun alẹnulọrọ laarin ilu, Ọtun Olubadan tilẹ Ibadan, gomina tẹlẹri, Raṣidi Adewọlu Ladọja, ẹni to tun ti mura silẹ lati de ade idẹ.”

“O n ya mi lẹnu nipa ohun ti awọn eeyan to ti n sọ oriṣiriṣi tẹlẹ yoo tun bẹrẹ sii kọ jade bayii. Gbogbo wa la nilo alaafia lati mu ipinlẹ yii siwaju, eyi lo si jẹ awọn adari meji logun.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI