Gómìnà AbdulRazaq fún akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe dáadáa jùlọ nínú ìdánwò 'WAEC' 2023 lẹbun owo nla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 11, 2024

Gómìnà AbdulRazaq fún akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe dáadáa jùlọ nínú ìdánwò 'WAEC' 2023 lẹbun owo nla


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fun akẹkọọ to ṣe daadaa julọ ninu idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama (WAEC) ti ọdun 2023 ni ẹbun iwe sọwedowo oni miliọnu kan naira.

Shalom Adeṣina lorukọ akẹkọọ naa to jẹ kẹkọọ jade nile ẹkọ girama ti Rehoboth College to wa lagbegbe Pipeline niluu Ilọrin.

Maaki akọkọ (A1) ni Adeṣina gba ninu gbogbo iṣẹ to ṣe ninu idanwo WAEC ọhun to jokoo ṣe lọdun to kọja.

Nigba to n ṣoju Gomina AbdulRazaq, kọmiṣanna feto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu lọjọ Abamẹta to kọja, sọ pe iwuri nla ni Adeṣina jẹ fun ipinlẹ Kwara.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe owo naa ni lati fun Adeṣina ni iwuri, ko le tubọ maa tẹsiwaju pẹlu aṣeyọri ninu eto ẹkọ rẹ lọjọ iwaju.

Bakan naa nigba to n gbe oriyin fun awọn olukọni lori akitiyan wọn lati mu ki ilọsiwaju ba iṣẹ ijọba, o ni akẹkọọ naa ti gbe ogo Kwara ga.

Ninu ọrọ tiẹ, kọmiṣanna feto iṣẹ akanṣe, Ọnarebu John Ọlanrewaju Bello fi idunnu rẹ han si ipinnu gomina lori bo ṣe fun akẹkọọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI