Èto ayẹyẹ ìkẹyìn fún Olóògbé Fọlá Achudume parí pẹ̀lú ìsìn ìdúpẹ́ lárá-ọ̀tọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 25, 2024

Èto ayẹyẹ ìkẹyìn fún Olóògbé Fọlá Achudume parí pẹ̀lú ìsìn ìdúpẹ́ lárá-ọ̀tọ̀


Ẹsẹ ko gbero ninu ijọ Victory Life Bible Church International, Life Cathedral, Victory City, to wa lopopona Ajẹbọ niluu Abẹokuta lonii ọjọ Aiku nibi ti wọn ti sẹ isin idupẹ lati fi kadi eto isinku iyawo oludasilẹ ijọ naa, Oloogbe Arabinrin Fọla Achudume.

Oriṣiriṣi orin ọpẹ ati iyin ni awọn ọmọ ijọ naa, mọlẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun lori igbe aye rere ti oloogbe naa lo ki ọlọjọ too de.

Apostle Lawrence Achudume to jẹ oludasilẹ naa fi imọ riri han si awọn ọmọ ijọ fun aduroti wọn, pẹlu bo ṣe ni lara awọn ipenija igbagbọ ni.


Pasitọ ijọ Chapel of Restoration, Pasitọ Simeon Agbolabori lo waasu, nibi to ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati ni ireti igbe aye to tun wa lẹyin iku, nitori pe iṣipopada lasan ni iku jẹ 

O tẹnumọ ọrọ rẹ pe o ṣe pataki lati maa ṣajọyọ awọn to ba ti lọ, nitori pe aye miran tun wa lẹyin iku.


Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe oloogbe naa jade laye nitori ibi ti ijọ naa ku si, tabi iwa ika inu ijọ, bi ko ṣe pe Ẹlẹdaa rẹ lo pe e sọdọ, to si sun laya rẹ.

Pasitọ Agbolabori rọ awọn ọmọ ijọ lati duro ṣinṣin, ki wọn si maa tẹle awọn ipa to fi lelẹ ko too ku.


Gbogbo awọn to sọrọ patapata lati ori awọn ọrẹ ti wọn jọ dagba, awọn ti wọn jọ lọ sile ẹkọ, awọn to n tọ sọna, awọn ojiṣẹ Ọlọrun ati awọn mọlẹbi ni wọn ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ko ipa manigbagbe nigba aye rẹ 

Awọn gbajugbaja olorin bii Lilian Nkeji ati Ayan Jesu ni wọn fi orin da awọn eeyan laraya, ti awọn aṣoju awọn ijọ kaakifi, awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ko si gbẹyin nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI