Ẹgbẹrun mejilelọgọta akẹkọọ jokoo fun idanwo 'Common Entrance' lọfẹẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 11, 2024

Ẹgbẹrun mejilelọgọta akẹkọọ jokoo fun idanwo 'Common Entrance' lọfẹẹ ni Kwara


Ko din ni ẹgbẹrun mejilelọgọta akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti wọn jokoo fun idanwo aṣewọle sile ẹkọ girama, iyẹn Common Entrance lọfẹẹ ni ipinlẹ Kwara.

Awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ to wa kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara ni wọn ti mu awọn akẹkọọ naa.

Gbogbo wọn si ni wọn yoo wọ ile ẹkọ girama lai daamu tabi san owo kankan, nitori ijọba ti yanju rẹ.

Kọmiṣanna feto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu, lo sọ eyi di mimọ niluu Ilọrin laipẹ yii.

Kawu sọ pe kaakiri awọn ibi ti wọn ya sọtọ fun idanwo ni awọn akẹkọọ naa ti kopa.

Hajia Modibbo Kawu, pẹlu ikọ akọwọrin rẹ lọ fun abẹwo bi idanwo ọhun ṣe lọ si l'awọn agbegbe ayasọtọ to wa nijọba ibilẹ Ilọrin, Oke-Ero, ati Ekiti.

Kawu ni lara ipinnu gomina lati mu irọrun ba eto ẹkọ ni owo sisan fun idanwo naa, lati fi rọ awọn obi ati alagbatọ lọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI