Ẹ san owó ìfẹ̀yìntì wa kó tó pẹ́ jù - Àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì nínú iṣẹ́ ológun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 15, 2024

Ẹ san owó ìfẹ̀yìntì wa kó tó pẹ́ jù - Àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì nínú iṣẹ́ ológun


Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti ninu iṣẹ ologun ti wọn kopa ninu ogun abẹle ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ ilẹ Naijira lati san owo ifẹyinti ati owo ajẹẹlẹ wọn.

Awọn oṣiṣẹ ologun naa ti wọn ko din ni mẹtalelọgọta ti wọn gba sinu iṣẹ ologun laaarin ọdun 1967 ati 1978 sọ pe awọn ko tii gba owo ifẹyinti, bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọ lu aworan 'N134.7 billion' naira lati fi san ajẹẹlẹ naa fun wọn lọdun 2020.

Ninu atejade ti akọwe ẹgbẹ naa, Alaaji Bello Oseni buwọ lu, o jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ologun fi ontẹ lu iforukọsilẹ wọn, iyẹn Military Pensioner Board lọdun 2023, ṣugbọn sibẹ, wọn ko san owo ọhun.

Atẹjade ọhun fi ye wa pe awọn oṣiṣẹ ologun ti wọn ti fẹyinti yii, ni ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrindinlọgọrin (76) si ọdun marunlelọgọrin (85).

O sọ pe gbogbo wọn lo n tiraka lati ri ọwọ mu lọ sẹnu, ti atijẹ si tun jẹ iṣoro fun wọn, ati pe pupọ ninu wọn lo n gbe ninu ile ti baba wọn kọ laarin ọdun 1920 ati 1930.

Wọn wa n rawọ ẹbẹ si Aarẹ, awọn aṣofin ati aṣoju-ṣofin, to fi mọ awọn agba amofin, ajafẹtọ-ọmọniyan lati da si ọrọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI