Dípò kí ilé ìjọsìn sọ òtítọ́, owó àti ọrọ̀ ayé ni wọ́n fi n wàásù lójoojúmọ́ - Ọ̀ṣínbàjò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 12, 2024

Dípò kí ilé ìjọsìn sọ òtítọ́, owó àti ọrọ̀ ayé ni wọ́n fi n wàásù lójoojúmọ́ - Ọ̀ṣínbàjò


Igbakeji aarẹ ana fun Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti sọ pe ohun kan ṣoṣo to le mu ki orileede naa ni ilọsiwaju ni ki awọn ile ijọsin bẹrẹ iwaasu nipa iṣẹ ṣiṣe, dipo owo ati ọrọ aye tan awọn eeyan jẹ.

Ọjọgbọn Ọṣinbajo toun naa jẹ pasitọ ninu ijọ Ridiimu ti Baba Adeboye lo sọrọ naa lasiko to n ṣe idanilẹkọọ nibi ayẹyẹ idasilẹ ọdun kejidinlaadọrin ati ipagọ ọdun kejidinlọgọta ti ijọ The Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, lopin ọsẹ to kọja yii.

Agba ojiṣẹ Ọlọrun naa jẹ ko di mimọ pe Naijiria yoo dide pada nigba ti awọn ijọ ba bẹrẹ sii waasu nipa pataki iṣẹ ṣiṣe, dipo owo ati ọrọ aye.

Nibẹ lo ti kọminu lori bi awọn ile ijọsin ṣe yi erongba wọn pada nipa iwaasu wọn pada kuro ni ṣiṣiṣẹ pẹlu ọkan akikanju, to si jẹ pe ọrọ aye ni wọn n le kiri.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ninu ọrọ rẹ, o sọ pe

“Fun igba pipẹ, ohun kan ti awọn ile ijọsin n ṣe ni kiko ọrọ aye jọ, ti wọn si gbagbe nipa ipe si iṣẹ iwaasu lati ṣagbelarugẹ alaafia, iṣọkan ati idagbasoke awujọ wa.

“To ba jẹ pe lotitọ la nifẹ sii pe ki Naijiria mu ayanmọ rẹ ṣẹ, ile ijọsin ni lati pada si ibẹrẹ pẹpẹ, nipa iwaasu nipa pataki iṣẹ akikanju, itara fun iṣẹ ati ṣiṣe iṣẹ isin fun agbegbe ẹni.

“Ọna kan ṣoṣo ti a le gba lati mu iwuri ba awọn eeyan wa, ki wọn si jẹ aṣoju gidi nipa ayipada iwuwasi, dipo ki wọn kan maa waasu ihinrere nipa owo lọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI