'Ó dá mi lójú pé ẹ máa tayọ lẹ́ka ètò ìlera lágbayé - AbdulRazaq sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ẹ̀kọ́ ètò ìlera - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 25, 2024

'Ó dá mi lójú pé ẹ máa tayọ lẹ́ka ètò ìlera lágbayé - AbdulRazaq sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ẹ̀kọ́ ètò ìlera


Gomina AbdulRahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ti sọrọ, to tun fọwọ sọya pe oun ni idaniloju wi pe awọn akẹkọọjade ti ile ẹkọ giga eleto ilera nipinlẹ naa, Kwara State College of Health Technology, Offa yoo ṣe daadaa ni gbogbo ibi ti wọn ba de lagbaye.

Gomina AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ nibi eto ayẹyẹ ikẹkọọjade to waye nile ẹkọ naa lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.

Eto ayẹyẹ ikẹkọọjade akọkọ ree latigba ti wọn ti da ile ẹkọ naa silẹ 

AbdulRazaq ti Kọmiṣanna feto ile ẹkọ giga, Mary Arinde ṣoju fun sọ pe nipa ẹkọ ti awọn akẹkọọ ọhun kọ, o da oun loju pe wọn yoo mu agbelarugẹ ba ẹka eto ilera Naijiria .

Bakan naa lo sọ pe iṣakoso oun farajin fun idagbasoke eto ẹkọ igbalode, paapaa leyi to nii ṣe pẹlu eto ilera.

"Mo kii yin ku oriire iṣẹ takuntakun lori aṣeyọri yin. Ifọkanjin ati ifarada lo gbe e yin de ibi ti ẹ wa lonii, nko si ṣe iyemeji wi pe ẹ maa tẹsiwaju lati maa ko ipa rere lẹka eto ilera," gomina lo sọ eyi.

"Ọjọ iwaju ẹka eto ilera lẹ jẹ nipinlẹ Kwara, a si mọ riri yii. Iṣakoso yii farajin fun idagbasoke ati agbelarugẹ eto ẹkọ to yanranti, paapaa to ba ti nii ṣe pẹlu eto ilera."



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI