Bí Osimhen bá darapọ̀ mọ́ Chelsea, ibẹ̀ ni ògo rẹ̀ yóò wọlẹ̀ sí - Wòlíì Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 15, 2024

Bí Osimhen bá darapọ̀ mọ́ Chelsea, ibẹ̀ ni ògo rẹ̀ yóò wọlẹ̀ sí - Wòlíì Ayọdele


Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti gba gbajugbaja agbabọọlu Naijiria nni, Victor Osimhen lamọran lati ma ṣe darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.

Wolii Ayọdele sọ pe bi Osimhen ba darapọ mọ ìkọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, ibẹ ni ọjọ iwaju rẹ nidi ere bọọlu alafẹsẹgba yoo ti dohun igbagbe.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bi oṣu meloo kan sẹyin ni Victor Osimhen to n gba ọwọ iwaju fun ẹgbẹ agbabọọlu Napoli ti di ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu loriṣiriṣi n fẹ lati ra.

Ọpọ ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu ni iroyin ti n lọ kaakiri wi pe wọn nifẹẹ lati ra ọmọ bibi ipinlẹ Eko naa, awọn si ni Chelsea, Arsenal, Paris Saint-Germain, Manchester United, ati Liverpool, to fi mọ awọn aarẹ.

Wolii Ayọdele ninu fọnran oniṣẹju mẹrinlelogoji to tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe ogo ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa ko nii buyọ to ba darapọ mọ Chelsea.

Bakan naa ni agba ojiṣẹ Ọlọrun naa tun fi kun ọrọ rẹ pe ki ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orileede Naijiria ma ṣe pe Osimhen mọ, to ba fi le darapọ mọ Chelsea, nitori pe yoo jẹ idiwọ fun wọn lati yege fun idije ife ẹyẹ agbaye ati ti Afrika.

“Mo fẹẹ tete gbe amọran yii sita gẹgẹ bi itọni ti mo gba wi pw ki Osimhen ma ṣe lọ Chelsea, nitori pe to ba lọ sibẹ, ogo rẹ ko nii tan, ati pe niṣe ni yoo pa ọjọ iwaju rẹ.”

“NFF, bi Osimhen ba fi le lọ si Chelsea, ẹ ma ṣe pe mọ, ati pe pipe e sinu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles nilo agbeyẹwo rẹ daadaa, nitori pe a ni gbogbo amuyẹ lati yege fun idije ife ẹyẹ agbaye ati tilẹ Afrika.”



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI