Bí ìròyìn ikú Àdùkẹ́ Gold ṣe jáde síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 13, 2024

Bí ìròyìn ikú Àdùkẹ́ Gold ṣe jáde síta


Titi di asiko ti a n ṣe akojọpọ iroyin yii, ni ọrọ iku gbajugbaja onkọrin ẹmi nni, Adukẹ Ajayi ti ọpọ mọ si Adukẹ Gold ṣi n jẹ fun ọpọ awọn ololufẹ obinrin naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe irọ, bẹẹ l'awọn miran n sọ pe awuyewuye lasan ni, ṣugbọn ṣa, Adukẹ Gold ti jade laye.

Odu ni Adukẹ Gold, kii ṣaimọ foloko lagboole onkọrin ẹmi lorileede Naijiria, oun si lo ko orin to ṣi n kaakiro titi di asiko yii, 'Nitori Ogo'.

Ọkan lara awọn onkkọrin ẹgbẹ rẹ, Esther Igbẹkẹle lo kede iroyin iku Adukẹ loju opo ayelujara rẹ, to si ni "Ọgagun kan ti ṣubu. Sun re o."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI