Ayé oooo! Wọ́n lọ́rọ Báálé ilé tó pokùnso l’Abẹ́òkúta kìí ṣojú lásán - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 31, 2024

Ayé oooo! Wọ́n lọ́rọ Báálé ilé tó pokùnso l’Abẹ́òkúta kìí ṣojú lásán


Kayeefi niṣẹlẹ baale ile kan, Oluwaṣeun Shorinọla ti wọn lo pokunso lagbegbe Kemta, Idi-Aba niluu Abẹokuta ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ, paapaa awọn mọlẹbi rẹ.

Shorinọla, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni wọn lo gbẹmi ara rẹ lojiji, lasiko tẹnikẹni ko si nitosi.

Alẹ Ọjọru tii ṣe Wẹside, ọsẹ ti a wa yii ni wọn deedee ri oku Shorinọla to n mi jolonjolo lori oke ninu yara rẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọrọ naa kii ṣoju lasan, ati pe ko ba ẹnikẹni sọrọ ohun to fa a to fi gbe igbesẹ akinkanju ọhun.

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla jẹ ko di mimọ pe otitọ ni, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii awọn.

Odutọla sọ pe iyawo ọkunrin naa lo ri ọkọ rẹ nibi to so ara rẹ kọ si, ko to di pe ẹlẹmin gba a.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2024, Temitọpẹ Oguntade lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Kemta, nibẹ lo ti ṣalaye pe oun gba ipe ori aago lati ọdọ Tajudeen Arẹmu wi pe aburo oun ti ku, ati pe iyawo rẹ lo ri oku naa.

“Awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati wo ohun to ṣẹlẹ. Nigba ti wọn debẹ, wọn rii pe Shorinọla ti ku, nibi to pokunso si, eyi to fi han pe o pokunso ni. Wọn gbe oku naa walẹ.

“Bi awọn ọlọpaa ṣe fẹ maa gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo, ni awọn mọlẹbi sọ pe awọn yoo lọ sinku rẹ, nitori pe ko tun nilo ayẹwo kankan mọ.”

Ṣugbọn ṣa, Odutọla sọ pe gbogbo bi nnkan ṣe n lọ lawọn n tọpinpin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI