Àyájọ́ àwọn ọ̀dọ́ lágbàáyé: Gómìnà AbdulRazaq ní kí àwọn ọ̀dọ́ dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 13, 2024

Àyájọ́ àwọn ọ̀dọ́ lágbàáyé: Gómìnà AbdulRazaq ní kí àwọn ọ̀dọ́ dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gba awọn ọdọ Naijiria lamọran lati dẹkun iwa ibajẹ lawujọ.

AbdulRazaq rọ awọn ọdọ lati maa fi ifẹ ati iṣọkan ba ara wọn lo, ki wọn si yago fun oniruuru iwa ibajẹ ati ọdaran, ki wọn si gbajumọ awọn ohun ti yoo ṣe anfaani rere fun ọjọ iwaju wọn.

Nigba to n sọrọ nibi akanṣe eto lati saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn ọdọ lagbaye niluu Ilọrin, gomina gbe oriyin fun awọn ọdọ Kwara lori bi wọn ṣe n gbe ogo ipinlẹ naa ga.

O ni awọn ọdọ Kwara maa n yago fun oniruuru iwa ti ko ba ti ọmọluwabi mu, bẹẹ si ni wọn kii da si awọn wahala to ba jẹ ti apapọ.

Aworan:














No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI