Àwòrán Ẹniọlá Badmus dá wàhálà sílẹ̀ lórí ayélujára, ló bá fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 9, 2024

Àwòrán Ẹniọlá Badmus dá wàhálà sílẹ̀ lórí ayélujára, ló bá fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀


Odu ni gbajugbaja oṣerebinrin nni, Ẹniọla Badmus, kii ṣaimọ foloko lagbo ere tiata lorileede Naijiria, ati kaakiri agbaye.

Pupọ awọn to mọ Ẹniọla Badmus pẹlu bo ṣe sanra tẹlẹ lo n ya lẹnu nigba to de lati ibi to ti lọ ṣe iṣẹ abẹ, lati din ara to san ku.

Ẹniọla Badmus lo ti bẹrẹ iṣẹ bayii gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ ọkan lara awọn minisita lorileede Naijiria.

Laipẹ yii ni oṣerebinrin naa gbe awọn aworan ara tuntun sori ikanni 'Instagram', leyi to ti da wahala silẹ bayii.

Bi Ẹniọla ṣe gbe awọn aworan naa jade, ni awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ sii sọrọ.

Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun un, bẹẹ ni awọn miran n bu ẹnu atẹ lu aworan naa.

Awọn kan sọ pe atunṣe ti Ẹniọla ṣe si aworan ara rẹ to gbe jade ti pọ ju, ti awọn miran si n sọ oriṣiriṣi.

Obinrin naa ti wa fibinu sọrọ si ọkan lara wọn, to si loun ri bi 'mama rẹ ṣe ri'.

Awọn aworan to gbe jade naa ree...




Ohun ti awọn eeyan n sọ ree...




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI