Àwọn wọ̀nyí fi orúkọ ọ̀ga EFCC, Ọlá Olókóyèdé lu jìbìtì mílíọ̀nù kan dọ́là - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 31, 2024

Àwọn wọ̀nyí fi orúkọ ọ̀ga EFCC, Ọlá Olókóyèdé lu jìbìtì mílíọ̀nù kan dọ́là



Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ti sọ pe awọn ti tẹ ọkunrin mẹrin kan lori ésun fifi orukọ ọga awọn, Ọla Olukoyede lu jibiti.

EFCC sọ pe awọn mẹrin ọhun n ba orukọ ọga awọn jẹ kaakiri nipasẹ iwa jibiti wọn.

Ninu atẹjade ti ajọ EFCC gbe jade lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, EFCC sọ pe olobo to tẹ awọn lọwọ lo jẹ kọwọ tẹ wọn.

Ojobo Joshua, Aliyu Hashim, Thomas Oduh ati Paul Ogiji ni awọn mẹrẹẹrin tọwọ tẹ l’Ọjọru tii ṣe Wẹside, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2024 lagbegbe Gimbiya, Garki and Apo Legislative Quarters, Abuja.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn mẹrin yii pe alakoso agba tẹlẹ fun ajọ Nigeria Port Authority, NPA, Ọgbẹni Mohammed Bello-Koko, nibi ti wọn ti n fẹsun iwa jibiti to ṣe lasiko to fi wa nipo kan an.

“Wọn sọ fun ọkunrin naa pe Olukoyede ti ba a pari ọrọ rẹ, ati pe yoo nilo lati san miliọnu kan owo dọla, tabi ki wọn fi kele ofin gbe e, ki wọn si foju rẹ ba ile-ẹjọ.

“Eyi lo jẹ ki ọkunrin naa gba ileeṣẹ ajọ EFCC lọ lati fi to wọn leti, ti awọn yẹn naa si bẹrẹ sii dọgbọn tẹle wọn, ko to di ọwọ palaba wọn segi, ti wọn si ti wa lahamọ.”

EFCC sọ pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI