Àwọn ‘ẹ̀gbọ́n àdúgbò’ lu Portable lálùbami lóko eré, ló bá bú sẹ́kún níta gbangba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2024

Àwọn ‘ẹ̀gbọ́n àdúgbò’ lu Portable lálùbami lóko eré, ló bá bú sẹ́kún níta gbangba


Asiko yii kii ṣe asiko to dara rara fun gbajugbaja olorin takasufee nni, Habeeb Okikiọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable, pẹlu bi awọn kan to pe ni ‘Ẹgbọn Adugbo’ ṣe luu lalubami.

Portable ati awọn ọmọ ẹyin rẹ la gbọ pe awọn eeyan naa lu, tọrọ si di ẹni ori yọ, o di ile fun wọn.

Funra Portable, ẹni to tun n pe ara rẹ ni ‘Were Olorin’ lo gbe ohun to ṣẹlẹ sori ikanni ayelujara laipẹ yii, to si n rawọ ẹbẹ pe ki wọn tu awọn ọmọ ẹyin oun silẹ.

Portable sọ pe alubami ti wọn lu oun ati awọn ọmọ ẹyin oun pọ debi wi pe wọn tun mu awọn kan sahamọ.

Ninu ohun to kọ, o ni “Wahala, iṣẹlẹ nla lagbegbe Iju Iṣaga nibi ti a ti lọ ṣajọyọ pẹlu @lincon_orn to n ta mọto ... Ninu adugbo ti a wa, ti a ti n ṣere ni awọn kan ti wọn pe ara wọn ni Ẹgbọn Adugbo wọle wa, ti wọn si kona iya fun wa.

“A ṣi n wa awọn bọisi ZEHNATION oo.. wọn kọlu awọn ọmọ ẹyin mi lẹyin ti mo na papa bora ... ki @lincon_orn ba wa sọ fun Ẹgbọn adugbo lati da iPhone meji to jẹ ti @iam_sexyshay ati kaadi ATM mi pada..

“A ri awọn foonu ati mọto @dullarboi … ṣugbọn a ko ri oun funra rẹ…Nko tii ri @bamidola_, a gbọ pe wọn kọlu oun naa .. awọn akọrin mi niyẹn ti a ṣi n wa wọn oo.

“Ọlọrun ko nii doju ti wa, eeyan burku ni awọn wọnyi, bi wọn ṣe lọ mi lọwọ gba niyẹn. Awọn Ẹgbọn adugbo yii gba ṣeeni (ice chain) mi, wọn tun gba iyẹri eti to jẹ goolu mi, lẹyin ti mo fi ifẹ han si gbogbo wọn, ti mo si fun wọn lowo mi, wọn tun fẹẹ gba baagi mi ... Ṣe ọta ni wọn ni abi ololufẹ”.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI