Anfaani ‘Ilẹ Baba Mi’ nipasẹ Adron Homes: Mimu iṣọkan ba awọn ọmọ Naijiria nipa jijogun ilẹ ati dukia - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 21, 2024

Anfaani ‘Ilẹ Baba Mi’ nipasẹ Adron Homes: Mimu iṣọkan ba awọn ọmọ Naijiria nipa jijogun ilẹ ati dukia


Iwuri nla lo jẹ fun awọn alakoso ileeṣẹ Adron Homes pẹlu bi wọn ṣe n ṣafihan anfaani ọtun ti wọn pe ni ‘Ilẹ Baba Mi’, eyi ti wọn pe ni “My Fatherland”.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Adeboye Abiodun to jẹ alakoso eto amuṣẹṣe ati iroyin fi sita, o jẹ ko di mimọ pe anfaani ti ko wọpọ leyi jẹ lati mu gbogbo ọmọ Naijiria sunmọ ibi ti wọn ti ṣẹ wa, iyẹn ilẹ abinibi wọn.

Ko nii ṣe pẹlu ibi yoowu ti o le wa, yala nilẹ Naijiria tabi loke-okun, agbekalẹ yoo di alafo to wa laarin awọn ẹkun nilẹ Naijiria, eyi ti yoo mu idagbasoke ba iṣọkan gbogbo eeyan fun ogo ilẹ naa.

“My Fatherland” kọja rira ilẹ nikan; o jẹ anfaani nla lati lẹnu ọrọ ni eyikeyi ẹkun mẹfa to so Naijiria papọ.

Boya o n wa ọna lati tọju ọjọ alẹ rẹ fun rere, tabi o n wa apẹẹrẹ rere lati fi lelẹ fun awọn ọmọ rẹ, eto yii wa fun ọ, ko si le ga o lara.

Gbobo agbegbe ti eto yii wa lo wuyi lati ra, ti ko si ga ni lara, awọn agbegbe naa jẹ eyi to fọkanbalẹ lati gbe, ti yoo si fun ọ ni igboya lati sọ pe “Niihinyii ni ilẹ Baba mi”.

Agbekalẹ nla ree lati ileeṣẹ Adron Homes lati mu iṣọkan, ibagbepọ alaafia tubọ maa jọba laarin gbogbo ẹya to wa ni Naijiria.

Pẹlu anfaani sisan ida ogoji (40%) ati ọna irọrun lati sanwo yooku fun oṣu mẹrinlelogun, asiko to dara ree lati dokoowo.

Awọn anfaani miran to tun fanimọra ni:

Bronze Category (10-20 plots): 40% discount, estate in an estate, estate naming from an existing list, and five free street naming slots.
Silver Category (51-100 plots): 40% discount, customised estate naming, 10 free street naming slots, and 2% off infrastructure fees.
Gold Category (101-150 plots): 50% discount in 6 months or 40% in 36 months, limited street naming slots, and 5% off infrastructure fees.
Diamond Category (151-200 plots): 50% discount in 12 months or 40% in 36 months, free customised street naming slots, and 10% off infrastructure fees.
Platinum Category (Above 200 plots): 50% discount in 24 months, unlimited free customised street naming slots, and 20% off infrastructure fees.

Oniruuru ẹka eto yii lo wa pẹlu ẹbun ọlọkan-o-jọkan, eyi ti yoo fun ọ ni iwuri lati fowo rẹ dokoowo pẹlu ifọkanbalẹ.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ, a kan si ileeṣẹ naa loju opo ayelujara wọn ti www.adronhomesproperties.com tabi ki ẹ pe 08138432335.

Bẹẹ si lẹ le lọ si eyikeyi ikanni ayelujara tabi ẹka ileeṣẹ wọn to wa lagbegbe yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI