Alébíoṣù, babaláwo tíátà ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe ìgbéyàwó fún ìgbà àkọ́kọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2024

Alébíoṣù, babaláwo tíátà ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe ìgbéyàwó fún ìgbà àkọ́kọ́


Ilu-mọn-ọn-ka oṣere tiata nni, Ọgbẹni Adewale Alebioṣu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Awolọjọọ ti sọ idi pataki to fi ṣegbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ ọjọ pipẹ.

Alebioṣu to filuu Abẹokuta nipinlẹ Ogun ṣe ibugbe ni iroyin rẹ n tan kaakiri ori ikanni ayelujara laipẹ yii wi pe ọkunrin naa ti ṣe igbeyawọ.

Nigba to n ba akọroyin kan sọrọ, Alebioṣu sọ pe kii ṣe pe oun ṣe igbeyawo pẹlu obinrin miran, bi ko ṣe pe oun ṣe e pẹlu obinrin to bimo foun.

Alebioṣu funra rẹ lo gbe fọnran ati awọn aworan ibi to ti ṣe igbeyawọ labẹ ofin pẹlu iyawo rẹ nileeṣẹ to n ri sọrọ eto igbeyawo to wa lagbegbe Ikoyi nipinlẹ Eko.

Ọkunrin naa ni o pẹ toun ti gbe obinrin naa sile, ṣugbọn ti awọn ko ṣe igbeyawo latigba naa.

Nigba to n sọ idi ti ko fi ṣe igbeyawo latigba ti wọn ti jọ n gbe papọ gẹgẹ bii ọkọ-atiyawo, ogbontarigi babalawo nidi iṣẹ tiata naa sọ pe nitori owo ti ko si nigba naa lo fa a, ati pe bi nnkan ṣe ri foun ni.

O sọ pe gbara toun ti gbe fọnran ati aworan naa sori ikanni ayelujara ti ‘Tiktok’ oun ni iroyin ti n lọ kaakiri, to si latigba naa lawọn eeyan ti n pe oun lati fidi rẹ mulẹ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe bonkẹlẹ lawọn ṣe igbeyawo naa, nitori pe awọn ko pariwo, ṣugbọn to sọ pe ki ọdun 2024 too pari, oun yoo gbe gbogbo eeyan fun eto igbeyawo alarinrin laarin oun ati ololufẹ oun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI