Gbajugbaja onkọrin nni, Ọmọwe Ayọọla Akinọla Michael ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Alayọ Melody Singer, lo ti tu diẹ lara awọn aṣiri iku to pa Adukẹ Ajayi ti awọn eeyan tun n pe ni Adukẹ Gold.
Alayọ Melody Singer lo tu aṣiri naa nirọlẹ Ọjọbọ, Tọside ana, nibi aṣalẹ awọn oṣere ti wọn ṣe fun Adukẹ Gold.
Ọkunrin naa sọ pe oloogbe ti gbe ara le awọn Wolii kọja afẹnusọ, to si lo wa lara ohun to ṣeku pa a.
Alayọ ni Adukẹ kii bo ẹnu fun awọn Wolii, to si ni awọn Wolii naa lo n dari igbesi aye rẹ.
“Ọrọ ti mo kan fẹẹ sọ fun awa eniyan, nitori pe iku Morounkọla dun mi pupọ-pupọ. Awọn ọmọ ẹyin rẹ mọ pe ti a ba ti wọle lati sọrọ nigba miran, awọn ọrọ to maa n lagbara la jọ maa n sọ.
“Ẹ ma jẹ ka sunmọ awọn wolii ju, ẹ ma jẹ ka sunmọ awọn wolii ju, ma ṣe gbe pasitọ lori kọja aaye. Ibi ti ọpọ ti sunmọ wolii ni wọn ti ta ogo rẹ fun aye.
“Ibi ti ẹlomiran ti sunmọ wolii ni wọn ti ta ẹmi rẹ. Ẹnikan wa, Funkẹ Gold loun naa n jẹ ni Ẹpẹ, oun naa nijamba ọkọ lagbegbe Sango nigba naa.
“Mi o mọ boya a ṣi ranti rẹ. Ṣe ẹ ri gbogbo awọn ti a n sunmọ yii lo ṣeku pa ọpọlọpọ. Wọn maa tan ẹ jẹ titi ni. Bibeli si jẹ ka mọ pe ‘ẹni to ba fi eniyan ẹlẹran ara ṣe igbẹkẹle, asan ni’.”
“Ọsan la fi n ṣiṣẹ, oru la fi n gbadura, iyẹn fun ẹni to ba mu ogo wa saye. Ẹni ti ko ba ti le gbadura laarin oru maa sọnu ni. Ma jẹ ki eeyan kan tan ẹ jẹ wi pe oun fẹẹ mu ẹ lọ si Abuja.
“Ọrọ iku Adukẹ Gold dun mi gan-an ni, nitori pe ko si ọjọ ti a ba ti sọrọ, igbe ni - ẹmi si ree, omi kii pẹ ẹ jabọ loju mi. Oriṣiriṣi ọrọ la maa sọ.
“Mo tiẹ maa n beere lọwọ rẹ pe ṣe ko ri ẹni to dẹnu ifẹ kọ ọ ni. Eleyi to ṣi lọ si London, mo sọo pe ko jokoo sibẹ, ko si yi igbe aye rẹ pada diẹ, nitori pe ko kuku si ọkọ, bẹẹ ni ko si ọmọ.
“O ṣee ṣe ko ri ẹlomiran nti ọna wọn jọ maa ba ara wọn dọgba. Ati pẹlu, bi ohunkohun ba n ṣe wa, ẹ ma jẹ ka bo ẹnu, ẹ jẹ maa sọ fawọn eeyan. Ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni tan wa pa wi pe a ko gbọdọ sọrọ wa fun ẹnikẹni, irọ ni wọn n pa.
“Ẹni to ti gba owo ẹmi rẹ lo maa sọ pe o ko gbọdọ sọ fun eeyan. Eniyan ti a ba finu han lo n fi ẹni han sita...
“Adukẹ Gold ni ogo pupọ. Lọjọ kan ti a jọ n sọrọ ni mo sọ fun un pe igi ko nii dagba labẹ igi. Bi mo ṣe wa yii, nko ni ọta, bẹẹ ni nko ni ọrẹ, ẹni to ba ki mi ni maa ki, ẹni ti ko ba ki mi, mo n ba temi lọ niyẹn...
Ẹkunrẹrẹ wa ninu fọnran yii:
No comments:
Post a Comment