Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC l’Ọ́yọ̀ọ́ kú lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2024

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC l’Ọ́yọ̀ọ́ kú lójijì


Alagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ọyọ, Amofin Isaac Ajiboye Ọmọdẹwu ti jade laye.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ akọroyin wa lọwọ ṣe sọ, irọlẹ ọjọ Aiku to kọja ni ọkunrin naa ku lẹni ọdun mọkanlelọgọta.

Ọsibitu kan nilẹ Amẹrika la gbọ pe Ọmọdẹwu ku si nibi to ti lọ gba itọju lori ailera ara rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu APC kẹdun
Nigba ti wọn n kẹdun iku alaga wọn, ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ ọyọ sọ pe adanu nla ni iku Ọmọdẹwu jẹ fun wọn.

APC si ni kii ṣe ẹgbẹ naa nikan lo padanu Ọmọdẹwu, bi ko ṣe gbogbo Naijiria lapapọ.

Siwaju sii ni wọn ṣalaye pe lati inu oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni ni Ọmọdẹwu ti lọ n gba itọju lori aisan naa, to si fi n to awọn ọrẹ rẹ ati alabaṣiṣẹpọ rẹ leti titi digba to fi mi eemi ikẹyin lọjọ Aiku naa.

 Ọmọ bibi ilu Otu naa ti ṣiṣẹ lawọn ileeṣẹ ijọba, to si tun jẹ kọmiṣanna laarin ọdun 2011 si 2019, lasiko iṣakoso Oloogbe Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.

Iroko nla lo wo lulẹ
“Iroko nla ti wo, ti aaye nla si ti ṣofo ninu ẹgbẹ oṣelu wa (APC). Awọkọṣe iwa irẹlẹ ni alaga wa jẹ, to si ni iwa tutu, ati ọkan ifẹ ti ko ni iwa imọtara-ẹni-nikan. Asiko to le koko lo di alaga wa, to si ko ipa ribiribi lati yanju awọn iṣoro ati adojukọ ẹgbẹ.

“O tiẹ tun jẹ abamọ fun wa lasiko to papoda yii nitori pe asiko ti igbesẹ lati pẹtu si awọn ti inu n bi bẹrẹ sii so eso rere lo jade laye yii.

“Nigba ti a n ba Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, alaga apapọ ẹgbẹ ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kẹdun, a n gbadura pe ki Ọlọrun ba wa tẹ ẹ si afẹfẹ rere, ko si fun awọn mọlẹbi, ọrẹ ati ojulumọ lọkan itunu.” APC Ọyọ sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI