Adron Homes – Òmìrán tó dá dúró láàárín ọ̀pọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 20, 2024

Adron Homes – Òmìrán tó dá dúró láàárín ọ̀pọ̀


Bi ẹ ba ri ileeṣẹ to n ṣowo ilẹ, ile ati oniruuru dukia, ti wọn si fi ifẹ awọn eeyan, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun sọkan, ẹ jẹ ka gbe oṣuba kare fun wọn, nitori pe wọn ko wọpọ rara.

Bi ẹ ba ri ileeṣẹ to n ṣowo dukia, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati di alafo to wa laarin olowo, ọlọrọ ati mẹkunnu, ko si ohun meji ti ẹ ni lati ṣe bi ko ṣe lati gbe sadankata fun wọn lọ.

Ileeṣẹ Adron Homes ko wọpọ lawujọ awọn ileeṣẹ ti wọn ṣagbekalẹ ile igbe igbalode, iyẹn Real Estate, paapaa lorileede Naijiria.

Eyii gan-an lo jẹ ki wọn wa loke tente laarin awọn akẹgbẹ wọn, ti wọn si tayọ gbogbo awọn to le sọ pe wọn fẹẹ ba wọn figagbaga.

Ọna irọrun ati igbalode ni ileeṣẹ Adron Homes n gba ṣagbekalẹ awọn ile wọn ti wọn n kọ-ta fawọn onibara wọn kaakiri Naijiria.

Bi wọn ṣe ni lẹkun Iwọ-Oorun Naijiria, naa ni wọn tun ni si ẹkun Ariwa ilẹ Naijiria, pẹlu awọn oṣiṣẹ akọṣẹmọṣẹ ti wọn ṣetan lati fọna han yin.

Oniruuru awọn ohun amayedẹrun, to le jẹ ki ẹmi eeyan gun dọjọ alẹ ni awọn alakoso Adron Homes ṣeto sawọn agbegbe ti ‘Estate’wọn wa.

Awokọṣe nla ni ileeṣẹ Adron Homes jẹ fun gbogbo ileeṣẹ ‘Real Estate’ to wa kaakiri ilẹ Naijiria, Afrika ati agbaye lapapọ, koda ti wọn tun jẹ aritọkasi.

Agbekalẹ nla yii ko ṣẹyin alaṣẹ, alakoso ati oludasilẹ ogbontarigi akọṣẹmọṣẹ ọmọ bibi ilu Rẹmọ, ipinlẹ Ogun nni, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing.

Ẹri ọlọkan-o-jọkan lawọn onibara ileeṣẹ Adron Homes kaakiri Naijiria ti sọ, ti wọn si n sọ fun ẹni ti ko gbọ, ti ẹni to ṣẹṣẹ n gbọ naa tun n kede ihinrere ileeṣẹ naa kaakiri.

Afojusun ileeṣẹ Adron Homes ni lati di alafo to wa laarin olowo, ọlọrọ ati mẹkunnu patapata nipa ile gbigbe lorileede Naijiria, ti ijọba Naijiria si tun fontẹ lu wọn.

Kolonka ni awọn oriṣiriṣi aami ẹyẹ ti awọn ileeṣẹ, ajọ, ẹgbẹ ati awọn eeyan ti fi da ileeṣẹ Adron Homes lọla, nipa iwa ọmọluabi ati otitọ ti wọn fi n ba awọn onibara wọn ṣe.

Oniruuru iranlọwọ lo wa nileeṣẹ Adron Homes, bii amọran, alaye lẹkunrẹrẹ, anfaani owo sisan diẹdiẹ ati bẹẹbẹẹlọ.

Lara awọn ohun to jẹ ki ileeṣẹ Adron Homes wa loke tente ni ti awọn agbegbe to jọju ti ‘Estate’ wọn wa kaakiri ipinlẹ Eko, Ogun, Ọyọ, Ọṣun, Ekiti, to ti mọ ilu Abuja ati awọn ipinlẹ yooku ni Naijiria, leyi to yatọ si inu igbo irunmọlẹ ti awọn akẹgbẹ wọn n pariwo lori redio ati tẹlifiṣan nipa oniruuru iwa jibiti.

Awọn to ti de awọn agbegbe bii Town Park and Gardens, Emurẹn Imọta; Eko City Park and Gardens, Lẹkki Ẹpẹ; Grandview Park and Gardens, Atan-Ọta; Treasure Parks and Gardens, Shimawa; ati Rehoboth Park and Gardens to wa ni Ibẹju-Lẹkki ni wọn le royin ohun ti oju wọn ri si rere.

Nileeṣẹ Adron Homes, ko pọn dandan lati jẹ olowo nla ki o to le d’onile lori, bi tọrọkọbọ ba ti n wọnu apo iṣuna rẹ, o ti lanfaani lati di onile lori nipasẹ oniruuru anfaani ti wọn ṣagbekalẹ rẹ.

Ọja to n ta warawara ni ileeṣẹ Adron Homes, ti ẹyin naa si gbọdọ debẹ lati jẹ anfaani, ki ẹ le kuro ninu ẹgbẹ ayalegbe si ẹgbẹ lanlọọdu.

Ẹ wa gbọ o, bi wọn ba n kọ orin awọn ‘awa lanlọọdu da’, ẹ ko gbọdọ sapamọ, ẹ gbọdọ ba wọn kọrin naa papọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI