Abẹokuta gbalejo bi wọn ṣe ṣẹyẹ ikẹyin fun Oloogbe Fọla Achudume - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 22, 2024

Abẹokuta gbalejo bi wọn ṣe ṣẹyẹ ikẹyin fun Oloogbe Fọla Achudume


Ẹsẹ ko gbero niluu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti ṣayẹyẹ ikẹyin fun Oloogbe Fọla Achudume to jẹ iyawo oludasilẹ ijọ Victory Life Bible Church, Apostle Lawrence Achudume.
 
Arabinrin Fọla lo jade laye ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, lẹyin aisan rampẹ.

Ara, ẹbi, ọrẹ, ojulumọ ati awọn afẹnifẹre, to fi mọ awọn ọmọ ijọ ọhun kaakiri agbaye ni wọn peju sibi eto ayẹyẹ ikẹyin naa to waye ninu ijọ VLBC to wa lopopona Ajebọ, Abẹokuta.
 
Yawọ si awọn wọnyi, awọn alẹnulọrọ lawujọ bii gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti igbakeji, Onimọ-ẹrọ Yetunde Ọnanuga ṣoju fun; Ọgbẹni Kayọde Akinmade to jẹ oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin ati awọn miran lo wa nibẹ.
 
Pupọ awọn to mọ oloogbe naa ni wọn royin ipa rere to ko lawujọ, paapaa lawujọ awọn obinrin ninu igbagbọ.

Bii awọn eeyan ṣe n royin ipa to ko lawujọ, bẹẹ lawọn miran n sọ ẹkọ ti wọn ri kọ lara rẹ nigba to wa laye, ti wọn si lo fi ipa rere lelẹ ki ọlọjọ too de.
 
Obinrin naa lo ipo rẹ lati fi da ajọ oluranlọwọ silẹ, nibi to ti n ṣaanu fun onile, alejo, ọmọde, agba, arugbo ati awọn ọdọ kaakiri agbaye.
 
Akitiyan rẹ gẹgẹ bi akikanju obinrin to n ro awọn obinrin ẹgbẹ rẹ lagbara ni pupọ awọn to mọ ọn ko le gbagbe, gẹgẹ bi wọn ṣe n royin.
 
Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ lawọn miran n gbera ṣanlẹ lasiko ti wọn n fi eeru fun eeru, erupẹ fun erupẹ ati ekuru fun ekuru.

Gomina Dapọ Abiọdun ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi aṣoju Kristi, to si ni bo tilẹ jẹ pe adanu nla ni ipapoda rẹ jẹ, sibẹ o gbe igbe aye to kun fun ireti ati akitiyan ni gbogbo ọna, paapaa ninu igbagbọ.
 
"Adanu nla ni ipapoda rẹ jẹ, ṣugbọn igbe aye rẹ jẹ awokọṣe ireti ati akitiyan fun ọpọ eeyan. O ti fi ipa rere manigbagbe silẹ ninu ijọ ati lawujọ," wọnyi ni Gomina Abiọdun sọ.

Ọkan lara awọn to mọ oloogbe naa, to jẹri si igbe aye rere rẹ sọ pe "Akitiyan rẹ lati ro awọn obinrin, ọdọ lagbara, ati igbiyanju lati fun awọn ọdọ ni ọrọ iṣiti, ati igbelarugẹ eto ẹkọ awọn eeyan ni yoo ṣi maa wa ninu iranti wọn titilai."

Iyawo omina ipinlẹ Ogun, Arabinrin Bamidele Abiọdun; Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Pasito Umo Eno; Wolii Isa El-Buba to jẹ oludasilẹ ijọ El Buba Outreach Ministry International naa ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi akikanju ninu igbagbọ.
 
Bakan naa ni gbajugbaja Pasitọ Fẹmi Emmanuel ti ijọ Livingspring Chapel International ati Refrend Funkẹ Adejumọ ti ijọ Agape Christian Ministries gbadura fun oloogbe naa, pẹlu bi wọn ṣe lo ja ija iṣẹgun ninu igbagbọ.
 






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI