AbdulRazaq lo mu awọn idagbasoke alara-gbayida wọ Kwara - Ẹmir ilu Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 22, 2024

AbdulRazaq lo mu awọn idagbasoke alara-gbayida wọ Kwara - Ẹmir ilu Ilọrin


Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti sọ pe ko sẹni to mu awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke alara-gbayida wọ ipinlẹ Kwara to kọja Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
 
Ọba alaye naa lo fidi ọrọ yii mulẹ lonii, Ọjọbọ tii ṣe Tọside niluu Ilọrin, lasiko ti awọn alanẹlọrọ ninu ijọba ṣa abẹwo sii ni aafin rẹ.

Lara awọn to wa nibi abẹwo ọhun ni: Komiṣanna fọrọ okoowo ati imọ-ẹrọ, Damilọla Yusuf-Adelọdun; Kọmiṣanna feto ayika, Nafisat Buge; alaga ileeṣẹ Kwara State Geographical Information Service, Alaaji Abdulkareem Suleiman; Akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye; amugbalẹgbẹ pataki si gomina lori akanṣe iṣẹ, Onimọ-ẹrọ Ladi Yusuf; ati awọn miran.
 
Nigba to n sọrọ, Ẹmir jẹ ko di mimọ pe, "Agbekalẹ atunṣe awọn iṣẹ idagbasoke lawọn igberiko ati ilu to n lọ lọwọ, ijọba Kwara ni atilẹyin wa, nitori pe wọn yẹ fun idagbasoke ati ilọsiwaju to lọọrin.
 
"Ọkan mi balẹ ori afojusun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq pẹlu awọn atunṣe ati fifẹ opopona kaakiri ipinlẹ yii, paapaa laarin ilu Ilọrin.
 
"Ohun to ṣe pataki, to si yẹ ni gomina n ṣe laarin ilu, paapaa olu-ilu ipinlẹ Kwar," Ẹmir sọrọ naa fun igbimọ ti Onimọ-ẹrọ Abdulquawiy Olododo to jẹ Kọmiṣanna feto iṣẹ ti oludamọran pataki fun gomina lori akanṣe iṣẹ, Alaaji Abdulrazaq Jiddah lewaju rẹ. 

"Mo gbọ, mo si ri awọn akanṣe iṣẹ opopona to n lọ kaakiri ilu, ati paapaa gẹgẹ bi ọba alaye ti mo jẹ, a maa tubọ maa gbaruku ti ijọba nipa adura lati ṣe aṣeyọri.
 
"Ohun to tọ lẹ n ṣe. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, awọn ipa ti gomina ti ko jẹ eyi to ṣafihan igbagbọ ninu ara ẹni. Nigba ti eeyan ba dawọ le iru akanṣe iṣẹ bẹẹ, ko tun nilo lati wo ohun ti awọn ọta n sọ.

"Lẹyin o rẹyin ni wọn yoo ṣẹṣẹ mọ riri awọn iṣẹ naa. Fun idi eyi, mo maa tubọ maa rọ yin lati tubọ maa tẹsiwaju si daadaa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI