AbdulRazaq di Sardauna tìlú Ìlọrin - IROYIN AWIKONKO

Friday, August 30, 2024

demo-image

AbdulRazaq di Sardauna tìlú Ìlọrin

IMG_ORG_1724996505043

Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti fi oye tuntun, Sardaunan tiluu Ilọrin da Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọla.

Ẹmir Sulu-Gambari sọ pe oun ko ṣai gbe oye naa fun gomina yii, bi ko ṣe ti awọn ipa rere to ti ko, eyi to jẹ ki ipinlẹ Kwara maa lewaju ni gbogbo ẹka.

Alaga igbimọ ọba alaye nipinlẹ Kwara ọhun ṣalaye pe ipa to jọju ni AbdulRazaq n ko lawujọ awọn ọba ati oloye, paapaa nipa aṣa ati iṣẹṣe iṣẹdalẹ ilu Ilọrin.

Gomina AbdulRazaq ni ẹnikeji ti yoo di ipo Sardauna ilu Ilọrin mu, lẹyin oloogbe Alaaji Umar Saro, ẹni to papoda lọdun diẹ sẹyin.

Ṣaaju asiko ni wọn ti fi oriṣiriṣi oye bii Sọludẹrọ tiluu Ọffa, Sadaukin tiluu Lafiagi, Kauran tiluu Kaiama ati Akorede tiluu Oro, to fi mọ awọn miran lọla.

IMG_ORG_1724996525782

IMG_ORG_1724996526085

IMG_ORG_1724996526345

IMG_ORG_1724996526550

IMG_ORG_1724996526859

IMG_ORG_1724996527108

IMG_ORG_1724996527312

IMG_ORG_1724996525508

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *