Ààrẹ Tinubu gbéra lọ France - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2024

Ààrẹ Tinubu gbéra lọ France


Lonii, ọjọ Aje, Mọnde ni aarẹ ilẹ Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti gbera lọ sorileede France.

Atẹjade ti oludamọran pataki fun aarẹ lori eto iroyin, Ajuri Ngelale fi sita lọjọ Aiku, Sannde ana jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Tinubu yoo pada si Naijiria lẹyin ohun to lọ ṣe nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Ngelale ko ṣalaye ohun ti aarẹ lọ ṣe, ṣugbọn sibẹ o jẹ ko di mimọ pe lori ọrọ Naijiria ni aarẹ ṣe n lọ.

“Aarẹ Tinubu yoo lọ si France lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, yoo gbera niluu Abuja, olu-ilu Naijiria. Aarẹ yoo pada lẹyin iṣẹ rampẹ to lọ ṣe ni France.”

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja, Wẹside ni aarẹ lọ sorileede Equatorial Guinea, to si lo ọjọ mẹta gbako nibẹ.

Arẹ Equatorial Guinea, Teodoro Mbasogo lo fiwe pe Aarẹ Tinubu, to si balẹ sibẹ ni deede agogo meji ọsan kọja iṣẹju meje.

Ni bayii, ko tii sẹni to le sọ pato igba tabi asiko ti Aarẹ yoo pada si Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI